10 o óo sì lọ gbé e fún baba yín, kí ó jẹ ẹ́, kí ó baà lè súre fún ọ, kí ó tó kú.”
11 Ṣugbọn Jakọbu dá Rebeka ìyá rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Onírun lára ni Esau, ẹ̀gbọ́n mi, n kò sì ní irun lára.
12 Ó ṣeéṣe kí baba mi fi ọwọ́ pa mí lára, yóo wá dàbí ẹni pé mo wá fi ṣe ẹlẹ́yà. Nípa bẹ́ẹ̀ n óo fa ègún sórí ara mi dípò ìre.”
13 Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ègún náà wá sí orí mi, ọmọ mi, ṣá gba ohun tí mo wí, kí o sì lọ mú àwọn ewúrẹ́ náà wá.”
14 Jakọbu bá lọ mú wọn wá fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì se irú oúnjẹ aládùn tí baba wọn fẹ́ràn.
15 Lẹ́yìn náà Rebeka mú aṣọ Esau, àkọ́bí rẹ̀, tí ó dára jùlọ, tí ó wà nílé lọ́dọ̀ rẹ̀, ó wọ̀ ọ́ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀.
16 Ó mú awọ ewúrẹ́ tí ó pa, ó fi bo ọwọ́ Jakọbu ati ibi tí ó ń dán ní ọrùn rẹ̀,