21 Noa mu àmupara ninu ọtí waini ọgbà rẹ̀, ó sì sùn sinu àgọ́ rẹ̀ ní ìhòòhò.
22 Hamu, baba Kenaani, rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò, ó lọ sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ mejeeji lóde.
23 Ṣemu ati Jafẹti bá mú aṣọ kan, wọ́n fà á kọ́ èjìká wọn, wọ́n fi ẹ̀yìn rìn lọ sí ibi tí baba wọn sùn sí, wọ́n sì dà á bò ó, wọ́n kọ ojú sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọn kò sì rí ìhòòhò baba wọn.
24 Nígbà tí ọtí dá lójú Noa, tí ó gbọ́ ohun tí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí i,
25 Ó ní,“Ẹni ègún ni Kenaani,ẹrú lásánlàsàn ni yóo jẹ́ fún àwọn arakunrin rẹ̀.”
26 Ó tún fi kún un pé,“Kí OLUWA Ọlọrun mi bukun Ṣemu,ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.
27 Kí Ọlọrun sọ ìdílé Jafẹti di pupọ,kí ó máa gbé ninu àgọ́ Ṣemu,ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.”