4 Lẹ́yìn náà, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri, láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Sibekai, ará Huṣati, pa ìran òmìrán kan, ará Filistia, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sipai, àwọn ará Israẹli bá ṣẹgun àwọn ará Filistia.
5 Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, Elihanani, ọmọ Jairi, pa Lahimi, arakunrin Goliati, ará Gati, tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ tóbi tó òpó òfì ìhunṣọ.
6 Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Gati. Ọkunrin gbọ̀ngbọ̀nràn kan wà níbẹ̀, ìka mẹfa ni ó ní ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan ati ní ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ òmìrán ni òun náà.
7 Nígbà tí ó ń fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe ẹlẹ́yà, Jonatani, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi bá pa á.
8 Ìran òmìrán, ará Gati ni àwọn mẹtẹẹta; Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ni ó sì pa wọ́n.