Kronika Kinni 21:10-16 BM

10 “Lọ sọ fún Dafidi pé, ‘OLUWA ní, nǹkan mẹta ni òun fi siwaju rẹ, kí o yan èyí tí o bá fẹ́ kí òun ṣe sí ọ ninu wọn.’ ”

11 Gadi bá lọ sọ́dọ̀ Dafidi ó lọ sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o yan èyí tí o bá fẹ́ ninu àwọn nǹkan mẹta wọnyi:

12 yálà kí ìyàn mú fún ọdún mẹta, tabi kí àwọn ọ̀tá rẹ máa lé ọ kiri, kí wọ́n sì máa fi idà pa yín fún oṣù mẹta, tabi kí idà OLUWA kọlù ọ́ fún ọjọ́ mẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn sọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ náà, kí angẹli Ọlọrun sì máa paniyan jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Sọ èyí tí o bá fẹ́, kí n lè mọ ohun tí n óo sọ fún ẹni tí ó rán mi.”

13 Nígbà náà ni Dafidi wí fún Gadi pé, “Ìdààmú ńlá dé bá mi, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Ọlọrun, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀; má jẹ́ kí n bọ́ sí ọwọ́ eniyan.”

14 Nítorí náà, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn sórí ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n kú sì jẹ́ ẹgbaa marundinlogoji (70,000) eniyan.

15 Ọlọrun rán angẹli kan pé kí ó lọ pa Jerusalẹmu run; ṣugbọn bí ó ti fẹ́ pa á run, OLUWA rí i, ó sì yí ọkàn pada, ó wí fún apanirun náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Angẹli OLUWA náà bá dúró níbi ìpakà Onani ará Jebusi.

16 Dafidi rí angẹli náà tí ó dúró ní agbede meji ayé ati ọ̀run, tí ó na idà ọwọ́ rẹ̀ sí orí Jerusalẹmu. Dafidi ati àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ bá dojúbolẹ̀.