1 Nígbà tí Dafidi dàgbà, tí ó di arúgbó, ó fi Solomoni, ọmọ rẹ̀ jọba lórí Israẹli.
2 Dafidi pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn alufaa ati àwọn Lefi jọ.
3 Ó ka gbogbo àwọn Lefi tí wọ́n jẹ́ ọkunrin tí wọ́n dàgbà tó ọmọ ọgbọ̀n ọdún sókè, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa mọkandinlogun (38,000).
4 Dafidi fún ẹgbaa mejila (24,000) ninu wọn ní iṣẹ́ ninu tẹmpili; ó ní kí ẹgbaata (6,000) máa ṣe àkọsílẹ̀ ati ìdájọ́ àwọn eniyan,
5 kí ẹgbaaji (4,000) máa ṣọ́nà, kí ẹgbaaji (4,000) sì máa yin OLUWA pẹlu oríṣìíríṣìí ohun èlò orin tí ọba pèsè.
6 Dafidi pín àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé ìdílé: ti Geriṣomu, ti Kohati, ati ti Merari.