Kronika Kinni 24:1-7 BM

1 Bí a ṣe pín àwọn ọmọ Aaroni nìyí: Aaroni ní ọmọkunrin mẹrin: Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.

2 Nadabu ati Abihu kú ṣáájú baba wọn láì bí ọmọ kankan. Nítorí náà, Eleasari, ati Itamari di alufaa.

3 Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari ati Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi pín àwọn ọmọ Aaroni sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn.

4 Àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé pọ̀ ninu àwọn ọmọ Eleasari ju ti Itamari lọ, nítorí náà, wọ́n pín àwọn ọmọ Eleasari sí abẹ́ àwọn baálé baálé mẹrindinlogun, wọ́n sì pín àwọn ọmọ Itamari sí abẹ́ àwọn baálé baálé mẹjọ. Bí wọ́n ṣe pín wọn kò sì fì sí ibìkan nítorí pé

5 gègé ni wọ́n ṣẹ́ tí wọ́n fi yàn wọ́n, nítorí pé, bí àwọn alámòójútó ìsìn ati alámòójútó iṣẹ́ ilé Ọlọrun ṣe wà ninu àwọn ìran Eleasari, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n wà ninu ti Itamari.

6 Ṣemaaya, akọ̀wé, ọmọ Netaneli, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó kọ orúkọ wọn sílẹ̀ níwájú ọba ati àwọn ìjòyè, ati Sadoku, alufaa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati àwọn baálé baálé ninu ìdílé àwọn alufaa, ati ti àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n bá ti mú ọ̀kan láti inú ìran Eleasari, wọn á sì tún mú ọ̀kan láti ìran Itamari.

7 Gègé tí wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́ mú Jehoiaribu, ekeji mú Jedaaya. Gègé sì mú àwọn yòókù wọnyi tẹ̀léra wọn báyìí: