1 Dafidi ati àwọn olórí ogun ya àwọn kan sọ́tọ̀ ninu àwọn ọmọ Asafu, Hemani ati ti Jedutuni láti máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fi dùùrù, ati hapu ati aro kọrin. Àkọsílẹ̀ àwọn tí a yàn ati iṣẹ́ wọn nìyí:
2 Lára àwọn ọmọ Asafu wọ́n yan Sakuri, Josẹfu, Netanaya, ati Asarela; wọ́n wà lábẹ́ àkóso Asafu, wọn a sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ àkóso ọba.
3 Àwọn ọmọ Jedutuni jẹ́ mẹfa: Gedalaya, Seri, ati Jeṣaaya; Ṣimei, Haṣabaya ati Matitaya, abẹ́ àkóso Jedutuni, baba wọn, ni wọ́n wà, wọn a sì máa fi dùùrù sọ àsọtẹ́lẹ̀ ninu orin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA.
4 Àwọn ọmọ Hemani ni: Bukaya, Matanaya, Usieli, Ṣebueli, ati Jerimotu, Hananaya, Hanani, Eliata, Gidaliti, ati Romamiti Eseri, Joṣibekaṣa, Maloti, Hotiri, ati Mahasioti.
5 Ọmọ Hemani, aríran ọba, ni gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Ọlọrun ṣe láti gbé Hemani ga; Ọlọrun fún un ní ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta.