13 Gègé ni wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé kọ̀ọ̀kan, láti mọ ẹnu ọ̀nà tí wọn yóo máa ṣọ́, wọn ìbáà jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ, wọn ìbáà sì jẹ́ eniyan pataki.
14 Ṣelemaya ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn. Sakaraya, ọmọ rẹ̀, olùdámọ̀ràn tí ó mòye, ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá.
15 Obedi Edomu ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà gúsù; àwọn ọmọ rẹ̀ ni a sì yàn láti máa ṣọ́ ilé ìṣúra.
16 Gègé mú Ṣupimu ati Hosa fún ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ati ẹnu ọ̀nà Ṣaleketi, ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sí òkè. Olukuluku àwọn aṣọ́nà ni ó ní àkókò iṣẹ́ tirẹ̀.
17 Àwọn eniyan mẹfa ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ní ojoojumọ, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà àríwá, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà gúsù, àwọn meji meji sì ń ṣọ́ ilé ìṣúra.
18 Fún àgọ́ tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ojú ọ̀nà, àwọn meji sì ń ṣọ́ àgọ́ alára.
19 Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà láti inú ìran Kora ati ti Merari.