24 Joabu, ọmọ Seruaya, bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn eniyan, ṣugbọn kò parí rẹ̀. Sibẹsibẹ ibinu OLUWA wá sórí Israẹli nítorí rẹ̀; nítorí náà, kò sí àkọsílẹ̀ fún iye àwọn ọmọ Israẹli ninu ìwé ìtàn ọba Dafidi.
25 Àwọn tí ń ṣe àkóso àwọn ohun ìní ọba nìwọ̀nyí: Asimafeti, ọmọ Adieli, ni alabojuto àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ọba. Jonatani, ọmọ Usaya, ni ó wà fún àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu àwọn ìlú kéékèèké, àwọn ìlú ńláńlá, àwọn ìletò ati àwọn ilé ìṣọ́.
26 Esiri, ọmọ Kelubu, ni alabojuto fún gbogbo iṣẹ́ oko dídá.
27 Ṣimei, ará Rama, ni ó wà fún àwọn ọgbà àjàrà. Sabidi, ará Ṣifimu, ni ó wà fún ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí.
28 Baali Hanani, ará Gederi, ni ó wà fún àwọn ọgbà olifi ati ti igi sikamore. Joaṣi ni ó wà fún ibi tí wọ́n ń kó òróró olifi pamọ́ sí.
29 Ṣitirai, ará Ṣaroni, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní Ṣaroni. Ṣafati, ọmọ Adila, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní àwọn àfonífojì.
30 Obili, ará Iṣmaeli, ni ó wà fún àwọn ràkúnmí. Jedeaya, ará Meronoti, ni ó wà fún àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Jasisi, ará Hagiri, sì jẹ́ alabojuto àwọn agbo aguntan.