Kronika Kinni 5:20-26 BM

20 Nígbà tí wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ gbà, wọ́n ṣẹgun àwọn ará Hagiriti ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn, nítorí wọ́n ké pe Ọlọrun lójú ogun náà, ó sì gbọ́ igbe wọn nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

21 Àwọn ẹran ọ̀sìn tí wọ́n kó lójú ogun nìwọ̀nyí: ẹgbaa mẹẹdọgbọn (50,000) ràkúnmí, ọ̀kẹ́ mejila lé ẹgbaarun (250,000) aguntan, ati ẹgbaa (2,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; wọ́n sì kó ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọkunrin lẹ́rú.

22 Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n pa, nítorí pé Ọlọrun ni ó jà fún wọn; wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn títí tí àwọn ará Asiria fi kó wọn lẹ́rú.

23 Ìdajì ẹ̀yà Manase ń gbé Baṣani, wọ́n pọ̀ pupọ; wọ́n tàn ká títí dé Baali Herimoni, Seniri, ati òkè Herimoni.

24 Àwọn Olórí ìdílé wọn nìwọ̀nyí: Eferi, Iṣi, Elieli, ati Asirieli; Jeremaya, Hodafaya ati Jahidieli, akikanju jagunjagun ni wọ́n, wọ́n sì jẹ́ olókìkí ati olórí ní ilé baba wọn.

25 Ṣugbọn àwọn ẹ̀yà náà ṣẹ Ọlọrun baba wọn, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa tí àwọn tí Ọlọrun parun nítorí wọn ń bọ.

26 Nítorí náà, Ọlọrun ta Pulu ọba Asiria ati Tigilati Pileseri ọba Asiria, nídìí láti gbógun ti ilẹ̀ náà; wọ́n bá kó àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase tí wọn ń gbé ìhà ìlà oòrùn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ Hala, Habori, Hara, ati ẹ̀bá odò Gosani títí di òní olónìí.