67 Àwọn ìlú ààbò tí wọ́n fún wọn, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká, ní agbègbè olókè Efuraimu nìwọ̀nyí; Ṣekemu, ati Geseri;
68 Jokimeamu ati Beti Horoni;
69 Aijaloni ati Gati Rimoni.
70 Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, wọ́n fún ìdílé àwọn ọmọ Kohati tí ó kù ní Aneri ati Bileamu, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.
71 Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká: Golani ní ilẹ̀ Baṣani, ati Aṣitarotu.
72 Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Isakari; wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ati Daberati;
73 Ramoti ati Anemu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.