8 Lẹ́yìn tí Ṣaharaimu ti kọ àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji, Huṣimu ati Baara sílẹ̀, ó fẹ́ Hodeṣi, ó sì bímọ ní ilẹ̀ Moabu.
9 Ọmọ meje ni Hodeṣi bí fún un: Jobabu, Sibia, Meṣa, ati Malikami,
10 Jeusi, Sakia ati Mirima. Gbogbo wọn jẹ́ baálé baálé ní ìdílé wọn.
11 Huṣimu náà bí ọmọkunrin meji fún un: Abitubu ati Elipaali.
12 Elipaali bí ọmọkunrin mẹta: Eberi, Miṣamu ati Ṣemedi. Ṣemedi yìí ni ó kọ́ àwọn ìlú Ono, Lodi, ati gbogbo àwọn ìletò tí ó yí wọn ká.
13 Beraya ati Ṣema ni olórí àwọn ìdílé tí wọn ń gbé ìlú Aijaloni, àwọn sì ni wọ́n lé àwọn tí wọn ń gbé ìlú Gati tẹ́lẹ̀ kúrò;
14 àwọn ọmọ Beraya ni: Ahio, Ṣaṣaki, ati Jeremotu,