26 OLUWA si wi fun Mose pe; Nà ọwọ́ rẹ si oju okun, ki omi ki o tun pada wá sori awọn ara Egipti, sori kẹkẹ́ wọn, ati sori ẹlẹṣin wọn.
27 Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si oju okun, okun si pada bọ̀ si ipò rẹ̀ nigbati ilẹ mọ́; awọn ara Egipti si sá lù u. OLUWA si bì awọn ara Egipti ṣubu lãrin okun.
28 Omi si pada, o si bò kẹkẹ́, ati awọn ẹlẹṣin, ati gbogbo ogun Farao ti o wọ̀ inu okun tọ̀ wọn lẹhin lọ; ọkanṣoṣo kò kù ninu wọn.
29 Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli rìn ni iyangbẹ ilẹ lãrin okun; omi si jẹ́ odi fun wọn li ọwọ́ ọtún, ati li ọwọ́ òsi wọn.
30 Bayi li OLUWA gbà Israeli là li ọjọ́ na lọwọ awọn ara Egipti; Israeli si ri okú awọn ara Egipti leti okun.
31 Israeli si ri iṣẹ nla ti OLUWA ṣe lara awọn ara Egipti: awọn enia na si bẹ̀ru OLUWA, nwọn si gbà OLUWA ati Mose iranṣẹ rẹ̀ gbọ́.