6 O si wipe, Emi li Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu. Mose si pa oju rẹ̀ mọ́; nitoriti o bẹ̀ru lati bojuwò Ọlọrun.
7 OLUWA si wipe, Nitõtọ emi ti ri ipọnju awọn enia mi ti o wà ni Egipti, mo si gbọ́ igbe wọn nitori awọn akoniṣiṣẹ wọn; nitoriti mo mọ̀ ibanujẹ wọn;
8 Emi si sọkalẹ wa lati gbà wọn lọwọ awọn ara Egipti, ati lati mú wọn goke ti ilẹ na wá si ilẹ rere ati nla, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin; si ibi ti awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi.
9 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, igbe awọn ọmọ Israeli dé ọdọ mi; emi si ti ri pẹlu, wahala ti awọn ọba Egipti nwahala wọn.
10 Nitorina wá nisisiyi, emi o si rán ọ si Farao, ki iwọ ki o le mú awọn enia mi, awọn ọmọ Israeli, lati Egipti jade wá.
11 Mose si wi fun Ọlọrun pe, Tali emi, ti emi o fi tọ̀ Farao lọ, ati ti emi o fi le mú awọn ọmọ Israeli jade lati Egipti wá?
12 O si wipe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ; eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ pe, emi li o rán ọ: nigbati iwọ ba mú awọn enia na lati Egipti jade wá, ẹnyin o sìn Ọlọrun lori oke yi.