23 Aaroni si fẹ́ Eliṣeba, ọmọbinrin Aminadabu, arabinrin Naṣoni, li aya; on si bí Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari fun u.
24 Ati awọn ọmọ Kora; Assiri, ati Elkana, ati Abiasafu; wọnyi ni idile awọn ọmọ Kora.
25 Eleasari ọmọ Aaroni si fẹ́ ọkan ninu awọn ọmọbinrin Putieli li aya; on si bi Finehasi fun u: wọnyi li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi ni idile wọn.
26 Wọnyi ni Aaroni on Mose na, ẹniti OLUWA sọ fun pe, Ẹ mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn.
27 Awọn wọnyi li o bá Farao ọba Egipti sọ̀rọ lati mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni Egipti: wọnyi ni Mose ati Aaroni na.
28 O si ṣe li ọjọ́ ti OLUWA bá Mose sọ̀rọ ni ilẹ Egipti,
29 Ni OLUWA sọ fun Mose wipe, Emi li OLUWA: sọ gbogbo eyiti mo wi fun ọ fun Farao ọba Egipti.