12 Nitorina a fi ọgbọ́n on ìmọ fun ọ, Emi o si fun ọ ni ọrọ̀, ọlá, tabi ọlà, iru eyiti ọba kan ninu awọn ti nwọn wà ṣaju rẹ kò ni ri, bẹ̃ni lẹhin rẹ kì yio si ẹniti yio ni iru rẹ̀.
13 Solomoni si pada lati ibi giga ti o wà ni Gibeoni wá si Jerusalemu, lati iwaju agọ ajọ awọn enia, o si jọba lori Israeli.
14 Solomoni ko kẹkẹ́ ati awọn ẹlẹṣin jọ: o si ni ẹgbãje kẹkẹ́ ati ẹgbãfa ẹlẹṣin, ti o fi sinu ilu kẹkẹ́ ati pẹlu ọba ni Jerusalemu.
15 Ọba si ṣe ki fadakà ati wura ki o wà ni Jerusalemu bi okuta, ati igi kedari li o ṣe ki o dabi igi sikamore ti o wà ni afonifoji fun ọ̀pọlọpọ.
16 A si mu ẹṣin wá fun Solomoni lati Egipti, ati okùn-ọ̀gbọ: awọn oniṣowo ọba ngbà okùn-ọ̀gbọ na ni iye kan.
17 Nwọn si gòke, nwọn si mu kẹkẹ́ kan lati Egipti wá fun ẹgbẹta ṣekeli fadakà, ati ẹṣin kan fun ãdọjọ: bẹ̃ni nwọn si nmu ẹṣin jade fun gbogbo awọn ọba ara Hitti, ati fun awọn ọba Siria nipa wọn.