2. Kro 19 YCE

Wolii Kan Bá Jehoṣafati Wí

1 JEHOṢAFATI, ọba Juda, si pada lọ si ile rẹ̀ ni Jerusalemu li alafia.

2 Jehu, ọmọ Hanani, ariran, si jade lọ ipade rẹ̀, o si wi fun Jehoṣafati pe, iwọ o ha ma ràn enia buburu lọwọ, iwọ o si fẹran awọn ti o korira Oluwa? njẹ nitori eyi ni ibinu ṣe de si ọ lati ọdọ Oluwa.

3 Ṣugbọn a ri ohun rere ninu rẹ, pe, nitori ti iwọ ti mu awọn ere-oriṣa kuro ni ilẹ na, ti o si mura ọkàn rẹ lati wá Ọlọrun.

Jehoṣafati Ṣe Àtúnṣe

4 Jehoṣafati si ngbe Jerusalemu: o nlọ, o mbọ̀ lãrin awọn enia lati Beerṣeba de òke Efraimu, o si mu wọn pada sọdọ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn.

5 O si fi awọn onidajọ si ilẹ na, ninu gbogbo ilu olodi Juda, lati ilu de ilu,

6 O si wi fun awọn onidajọ pe, Ẹ kiyesi ohun ti ẹnyin nṣe! nitori ti ẹnyin kò dajọ fun enia bikòṣe fun Oluwa, ti o wà pẹlu nyin ninu ọ̀ran idajọ.

7 Njẹ nisisiyi, jẹ ki ẹ̀ru Oluwa ki o wà lara nyin, ẹ ma ṣọra, ki ẹ si ṣe e; nitoriti kò si aiṣedede kan lọdọ Oluwa Ọlọrun wa, tabi ojuṣaju enia, tabi gbigba abẹtẹlẹ.

8 Pẹlupẹlu ni Jerusalemu, Jehoṣafati yàn ninu awọn ọmọ Lefi, ati ninu awọn alufa, ati ninu awọn olori awọn baba Israeli, fun idajọ Oluwa, ati fun ẹjọ; nwọn si ngbe Jerusalemu.

9 O si kilọ fun wọn, wipe, Bayi ni ki ẹnyin ki o mã ṣe, ni ibẹ̀ru Oluwa, li otitọ, ati pẹlu ọkàn pipé.

10 Ẹjọ ki ẹjọ ti o ba si de ọdọ nyin lati ọdọ awọn arakunrin nyin ti ngbe ilu wọn, lãrin ẹ̀jẹ on ẹ̀jẹ, lãrin ofin pẹlu aṣẹ, ìlana ati ẹtọ́, ki ẹnyin ki o kilọ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe dẹṣẹ si Oluwa, ibinu a si wá sori nyin, ati sori awọn arakunrin nyin: ẹ ṣe bẹ̃ gẹgẹ, ẹnyin kì yio si jẹbi.

11 Si wõ, Amariah, alufa ni olori lori nyin ni gbogbo ọ̀ran Oluwa; ati Sebadiah, ọmọ Iṣmaeli, alakoso ile Juda, fun ọ̀ran ọba; pẹlupẹlu ẹnyin ni olutọju awọn ọmọ Lefi pẹlu nyin. Ẹ mu ara le, ki ẹ si ṣe, Oluwa yio pẹlu ẹni-rere.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36