2. Kro 23 YCE

Wọ́n Dìtẹ̀ Mọ́ Atalaya

1 ATI li ọdun keje, Jehoiada mu ọkàn le, o si ba awọn olori ọrọrún dá majẹmu pẹlu, ani Asariah, ọmọ Jerohamu ati Iṣmaeli, ọmọ Jehohanani, ati Asariah ọmọ Obedi, ati Maaseiah, ọmọ Adaiah, ati Eliṣafati ọmọ Sikri.

2 Nwọn si lọ kakiri ni Juda, nwọn si kó awọn ọmọ Lefi jọ lati inu gbogbo ilu Juda, ati olori awọn baba ni Israeli, nwọn si wá si Jerusalemu.

3 Gbogbo ijọ enia si ba ọba dá majẹmu ni ile Ọlọrun. O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, ọmọ ọba ni yio jọba, gẹgẹ bi Oluwa ti wi niti awọn ọmọ Dafidi.

4 Eyi li ohun ti ẹnyin o ṣe; Idamẹta nyin yio wọle li ọjọ isimi, ninu awọn alufa ati ninu awọn ọmọ Lefi, ti yio ṣe adena iloro;

5 Idamẹta yio wà ni ile ọba: idamẹta yio si wà ni ẹnu-ọ̀na ti a npè ni ile Ipilẹ: ati gbogbo enia yio wà li àgbala ile Oluwa.

6 Ṣugbọn ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o wọ̀ ile Oluwa wá, bikoṣe awọn alufa, ati awọn ti nṣe iranṣẹ fun awọn ọmọ Lefi: nwọn o wọle, nitori mimọ́ ni nwọn: gbogbo awọn enia yio si ṣọ́ ẹṣọ́ Oluwa.

7 Awọn ọmọ Lefi yio yi ọba ka kakiri, olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀: ẹnikẹni ti o ba wá si iha ile na, a o si pa a: ṣugbọn ki ẹnyin ki o wà pẹlu ọba, nigbati o ba nwọ̀ ile, ati nigbati o ba njade.

8 Bẹ̃li awọn ọmọ Lefi ati gbogbo Juda ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada, alufa ti pa á ni aṣẹ, olukuluku si mu awọn enia rẹ̀ ti o nwọle li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti o njade li ọjọ isimi nitori Jehoiada alufa, kò jọwọ awọn ẹgbẹ meji alufa lọwọ lọ.

9 Jehoiada alufa, si fi ọ̀kọ ati asà, ati apata wọnni ti iti ṣe ti Dafidi ọba, ti o ti wà ni ile Ọlọrun, fun awọn balogun ọrọrun.

10 O si tò gbogbo awọn enia tì ọba kakiri olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀, lati apa ọtún ile na titi de apa òsi ile na, lẹba pẹpẹ ati lẹba ile na.

11 Nigbana ni nwọn mu ọmọ ọba jade wá, nwọn si fi ade fun u ati iwe ẹri na, nwọn si fi i jọba: Jehoiada ati awọn ọmọ rẹ̀ si fi ororo yàn a, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ.

12 Nigbati Ataliah gbọ́ ariwo awọn enia, ti nwọn nsare lọ sibẹ, ti nwọn si nyìn ọba, o si tọ awọn enia na wá sinu ile Oluwa:

13 O si wò, si kiyesi i, ọba duro ni ibuduro rẹ̀ li ẹba ẹnu-ọ̀na, ati awọn balogun ati awọn afunpè lọdọ ọba: ati gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè, ati awọn akọrin pẹlu ohun-elo orin, ati awọn ti nkede lati kọ orin iyin. Nigbana ni Ataliah fa aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe: Ọ̀tẹ! Ọ̀tẹ!

14 Nigbana ni Jehoiada alufa mu awọn olori ọrọrun ani awọn olori ogun na jade, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade kuro ninu ile sẹhin àgbala: ẹni-kẹni ti o ba si tọ̀ ọ lẹhin, ni ki a fi idà pa. Nitori alufa wipe, Ẹ máṣe pa a ninu ile Oluwa.

15 Nwọn si fi àye fun u; nigbati o si de atiwọ̀ ẹnu-ọ̀na Ẹṣin ile ọba, nwọn si pa a nibẹ.

Jehoiada Ṣe Àtúnṣe

16 Jehoiada dá majẹmu lãrin on ati lãrin awọn enia, ati lãrin ọba pe, enia Oluwa li awọn o ma ṣe.

17 Gbogbo awọn enia na si lọ si ile Baali, nwọn si wó o lulẹ, nwọn si fọ pẹpẹ ati awọn ere rẹ̀ tũtu, nwọn si pa Mattani alufa Baali, niwaju pẹpẹ.

18 Jehoiada si fi iṣẹ itọju ile Oluwa le ọwọ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ti Dafidi ti pin lori ile Oluwa, lati ma ru ẹbọ ọrẹ sisun Oluwa, bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, pẹlu ayọ̀ ati pẹlu orin lati ọwọ Dafidi.

19 O si fi awọn adena si ẹnu-ọ̀na ile Oluwa, ki ẹni alaimọ́ ninu ohun-kohun ki o má ba wọ̀ ọ.

20 O si mu awọn olori-ọrọrun, ati awọn ọlọla, ati awọn bãlẹ ninu awọn enia ati gbogbo enia ilẹ na, nwọn si mu ọba sọ̀kalẹ lati ile Oluwa wá: nwọn si gbà ẹnu-ọ̀na giga wá sinu ile ọba, nwọn si gbé ọba ka ori itẹ ijọba na.

21 Gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀: ilu na si tòro lẹhin ti a fi idà pa Ataliah.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36