2. Kro 20 YCE

Wọ́n Gbógun ti Edomu

1 O SI ṣe, lẹhin eyi li awọn ọmọ Moabu, ati awọn ọmọ Ammoni, ati ninu awọn ọmọ Edomu pẹlu wọn, gbé ogun tọ Jehoṣafati wá.

2 Nigbana li awọn kan wá, nwọn si wi fun Jehoṣafati pe, Ọ̀pọlọpọ enia mbo wá ba ọ lati apakeji okun lati Siria, si kiyesi i, nwọn wà ni Hasason-Tamari ti iṣe Engedi.

3 Jehoṣafati si bẹ̀ru, o si fi ara rẹ̀ si ati wá Oluwa, o si kede àwẹ ja gbogbo Juda.

4 Juda si kó ara wọn jọ, lati wá iranlọwọ lọwọ Oluwa: pẹlupẹlu nwọn wá lati inu gbogbo ilu Juda lati wá Oluwa,

5 Jehoṣafati si duro ninu apejọ enia Juda ati Jerusalemu, ni ile Oluwa, niwaju àgbala titun.

6 O si wipe, Oluwa, Ọlọrun awọn baba wa, iwọ kọ́ ha ni Ọlọrun li ọrun? Iwọ kọ́ ha nṣakoso lori gbogbo ijọba awọn orilẹ-ède? lọwọ rẹ ki agbara ati ipá ha wà, ti ẹnikan kò si, ti o le kò ọ loju?

7 Iwọ ha kọ́ Ọlọrun wa, ti o ti le awọn ara ilẹ yi jade niwaju Israeli enia rẹ, ti o si fi fun iru-ọmọ Abrahamu, ọrẹ rẹ lailai?

8 Nwọn si ngbe inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ibi-mimọ́ fun ọ ninu rẹ̀ fun orukọ rẹ, pe,

9 Bi ibi ba de si wa, bi idà, ijiya tabi àjakalẹ-àrun, tabi ìyan, bi awa ba duro niwaju ile yi, ati niwaju rẹ, (nitori orukọ rẹ wà ni ile yi): bi a ba ke pè ọ ninu wàhala wa, nigbana ni iwọ o gbọ́, iwọ o si ṣe iranlọwọ.

10 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, ati awọn ara òke Seiri, ti iwọ kò jẹ ki Israeli gbogun si nigbati nwọn jade ti ilẹ Egipti wá, ṣugbọn nwọn yipada kuro lọdọ wọn, nwọn kò si run wọn;

11 Si kiyesi i, bi nwọn ti san a pada fun wa; lati wá le wa jade kuro ninu ini rẹ, ti iwọ ti fi fun wa lati ni.

12 Ọlọrun wa! Iwọ kì o ha da wọn lẹjọ? nitori awa kò li agbara niwaju ọ̀pọlọpọ nla yi, ti mbọ̀ wá ba wa; awa kò si mọ̀ eyi ti awa o ṣe: ṣugbọn oju wa mbẹ lara rẹ.

13 Gbogbo Juda si duro niwaju Oluwa, pẹlu awọn ọmọ wẹrẹ wọn, obinrin wọn, ati ọmọ wọn.

14 Ṣugbọn lori Jahasieli, ọmọ Sekariah, ọmọ Benaiah, ọmọ Jeieli, ọmọ Mattaniah, ọmọ Lefi kan ninu awọn ọmọ Asafu, ni ẹmi Oluwa wá li ãrin apejọ enia na.

15 O si wipe, Ẹ tẹti silẹ, gbogbo Judah, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu, ati iwọ Jehoṣafati ọba; Bayi li Oluwa wi fun nyin, Ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya nitori ọ̀pọlọpọ enia yi; nitori ogun na kì iṣe ti nyin bikòṣe ti Ọlọrun.

16 Lọla sọ̀kalẹ tọ̀ wọn: kiyesi i, nwọn o gbà ibi igòke Sisi wá; ẹnyin o si ri wọn ni ipẹkun odò na, niwaju aginju Jerueli.

17 Ẹnyin kò ni ijà li ọ̀ran yi; ẹ tẹgun, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri igbala Oluwa lọdọ nyin, iwọ Juda ati Jerusalemu: ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya: lọla, ẹ jade tọ̀ wọn: Oluwa yio si pẹlu nyin.

18 Jehoṣafati tẹ ori rẹ̀ ba silẹ: ati gbogbo Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu wolẹ niwaju Oluwa lati sìn Oluwa.

19 Awọn ọmọ Lefi, ninu awọn ọmọ Kohati ati ninu awọn ọmọ Kori si dide duro, lati fi ohùn rara kọrin iyìn soke si Oluwa Ọlọrun Israeli.

20 Nwọn si dide ni kutukutu owurọ, nwọn si jade lọ si aginju Tekoa: bi nwọn si ti jade lọ, Jehoṣafati duro, o si wipe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ará Juda, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu. Ẹ gbà Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́, bẹ̃li a o fi ẹsẹ nyin mulẹ; ẹ gbà awọn woli rẹ̀ gbọ́, bẹ̃li ẹnyin o ṣe rere.

21 O si ba awọn enia na gbero, o yàn awọn akọrin si Oluwa, ti yio ma yìn ẹwa ìwa-mimọ́ bi nwọn ti njade lọ niwaju ogun na, ati lati ma wipe, Ẹ yìn Oluwa: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.

22 Nigbati nwọn bẹ̀rẹ si ikọrin ati si iyìn, Oluwa yàn ogun-ẹhin si awọn ọmọ Ammoni, Moabu ati awọn ara òke Seiri, ti o wá si Juda, a si kọlù wọn.

23 Awọn ọmọ Ammoni ati Moabu si dide si awọn ti ngbe òke Seiri, lati pa, ati lati run wọn tũtu: nigbati nwọn si pa awọn ti ngbe òke Seiri run tan, ẹnikini nṣe iranlọwọ lati run ẹnikeji.

24 Nigbati Juda si de iha ile-iṣọ li aginju, nwọn wò awọn ọ̀pọlọpọ enia, si kiyesi i, okú ti o ṣubu lulẹ ni nwọn, ẹnikan kò sá asalà.

25 Nigbati Jehoṣafati ati awọn enia rẹ̀ de lati kó ikogun wọn, nwọn ri lara wọn ọ̀pọlọpọ ọrọ̀, ati okú, ati ohun-elo iyebiye, nwọn si kójọ fun ara wọn, jù eyiti nwọn le kó lọ: nwọn si kó ikogun wọn jọ ni ijọ mẹta, nitoriti o sa papọ̀ju.

26 Ati li ọjọ kẹrin nwọn kó ara wọn jọ li afonifoji Ibukún, nitori nibẹ ni nwọn fi ibukún fun Oluwa, nitorina ni a ṣe npe orukọ ibẹ na ni, Afonifoji Ibukún, titi di oni.

27 Nigbana ni nwọn yipada, gbogbo awọn ọkunrin Juda ati Jerusalemu, ati Jehoṣafati niwaju wọn lati pada lọ si Jerusalemu pẹlu ayọ̀; nitori ti Oluwa ti mu wọn yọ̀ lori awọn ọta wọn.

28 Nwọn si wá si Jerusalemu pẹlu ohun-elo orin, ati duru ati ipè si ile Oluwa.

29 Ibẹ̀ru Ọlọrun si wà lara gbogbo ijọba ilẹ wọnni, nigbati nwọn gbọ́ pe Oluwa ti ba awọn ọta Israeli jà.

30 Bẹ̃ni ijọba Jehoṣafati wà li alafia: nitoriti Ọlọrun rẹ̀ fun u ni isimi yikakiri.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Jehoṣafati

31 Jehoṣafati si jọba lori Juda: o si wà li ẹni ọdun marundilogoji, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹdọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Asuba, ọmọbinrin Ṣilhi.

32 O si rìn li ọ̀na Asa, baba rẹ̀, kò si yà kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyi ti o tọ́ li oju Oluwa.

33 Sibẹ kò mu ibi giga wọnni kuro: pẹlupẹlu awọn enia na kò si fi ọkàn wọn fun Ọlọrun awọn baba wọn rara.

34 Ati iyokù iṣe Jehoṣafati, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyẹsi i, a kọ wọn sinu iwe Jehu, ọmọ Hanani, a si ti fi i sinu iwe awọn ọba Israeli.

35 Ati lẹhin eyi ni Jehoṣafati, ọba Juda, dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Ahasiah, ọba Israeli, ẹniti o ṣe buburu gidigidi:

36 O si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ ọ lati kan ọkọ̀ lati lọ si Tarṣiṣi: nwọn si kàn ọkọ̀ ni Esion-Geberi.

37 Nigbana ni Elieseri ọmọ Dodafah ti Mareṣa sọtẹlẹ si Jehoṣafati wipe, Nitori ti iwọ ti dá ara rẹ pọ̀ mọ Ahasiah, Oluwa ti ba iṣẹ rẹ jẹ. Awọn ọkọ̀ na si fọ́, nwọn kò si le lọ si Tarṣiṣi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36