1 ẸNI ọdun mẹdọgbọn ni Amasiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkandilọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jehoaddani ti Jerusalemu.
2 O si ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe pẹlu ọkàn pipé.
3 O si ṣe, nigbati a fi idi ijọba na mulẹ fun u, o pa awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o pa ọba, baba rẹ̀,
4 Ṣugbọn kò pa awọn ọmọ wọn, ṣugbọn o ṣe gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin ninu iwe Mose, ti Oluwa ti paṣẹ wipe, Awọn baba kì yio kú fun awọn ọmọ, bẹ̃li awọn ọmọ kì yio kú fun awọn baba, ṣugbọn olukuluku ni yio kú nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
5 Amasiah si kó Juda jọ, o si tò wọn lẹsẹsẹ gẹgẹ bi ile baba wọn, awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati balogun ọrọrun, ani gbogbo Juda ati Benjamini, o si ka iye wọn lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̀ lọ, o si ri wọn li ọkẹ mẹdogun enia ti a yàn, ti o le jade lọ si ogun, ti o si le lo ọ̀kọ ati asà.
6 O si bẹ̀ ọkẹ marun ogun alagbara akọni ọkunrin lati inu Israeli wá fun ọgọrun talenti fadakà.
7 Ṣugbọn enia Ọlọrun kan tọ̀ ọ wá, wipe, Ọba, máṣe jẹ ki ogun Israeli ki o ba ọ lọ: nitoriti Oluwa kò wà pẹlu Israeli, ani gbogbo awọn ọmọ Efraimu.
8 Ṣugbọn bi iwọ o ba lọ, ma lọ, mu ara le fun ogun na: Ọlọrun yio bì ọ ṣubu niwaju ọta: Ọlọrun sa li agbara lati ṣe iranlọwọ, ati lati bì ni ṣubu.
9 Amasiah si wi fun enia Ọlọrun na pe, Ṣugbọn kili awa o ha ṣe nitori ọgọrun talenti ti mo ti fi fun ẹgbẹ-ogun Israeli? Enia Ọlọrun na si dahùn pe, O wà li ọwọ Oluwa lati fun ọ li ọ̀pọlọpọ jù eyi lọ.
10 Nigbana li Amasiah yà wọn, ani ẹgbẹ-ogun ti o ti tọ̀ ọ lati Efraimu wá, lati tun pada lọ ile wọn: ibinu wọn si ru gidigidi si Juda, nwọn si pada si ile wọn ni irunu.
11 Amasiah si mu ara le, o si kó awọn enia rẹ̀ jade, o si lọ si afonifoji iyọ̀, o si pa ẹgbarun ninu awọn ọmọ Seiri.
12 Ati ẹgbãrun alãye li awọn ọmọ Juda kó ni igbekun lọ, nwọn si mu wọn lọ si òke apata na, nwọn si tãri wọn silẹ lati òke apata na, nwọn si fọ́ tũtu.
13 Ṣugbọn awọn ọmọ-ogun ti Amasiah ran pada lọ, ki nwọn ki o máṣe ba on lọ si ogun, kọlù awọn ilu Juda lati Samaria titi de Bet-horoni, nwọn si pa ẹgbẹdogun ninu wọn, nwọn si kó ikógun pipọ.
14 O si ṣe lẹhin ti Amasiah ti ibi pipa awọn ara Edomu bọ̀, o si mu awọn oriṣa awọn ọmọ Seiri bọ̀, o si gà wọn li oriṣa fun ara rẹ̀, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba niwaju wọn, o si sun turari fun wọn.
15 Nitorina ni ibinu Oluwa ru si Amasiah, o si ran woli kan si i, ti o wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi nwá oriṣa awọn enia na, ti kò le gbà awọn enia wọn lọwọ rẹ?
16 O si ṣe bi o ti mba a sọ̀rọ, ọba si wi fun u pe, A ha fi ọ ṣe igbimọ̀ ọba bi? fi mọ: ẹ̃ṣe ti a o fi pa ọ? Nigbana ni woli na fi mọ; o si wipe, Emi mọ̀ pe, Ọlọrun ti pinnu rẹ̀ lati pa ọ run, nitoriti iwọ ti ṣe eyi, ti iwọ kò si tẹ eti si imọ̀ran mi.
17 Nigbana ni Amasiah, ọba Juda, gbà ẹ̀kọ, o si ranṣẹ si Joaṣi ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu ọba Israeli, wipe, Wá, jẹ ki a wò ara wa li oju.
18 Joaṣi, ọba Israeli, si ranṣẹ si Amasiah, ọba Judah, wipe, Ẹgun-ọ̀gan ti o wà ni Lebanoni ranṣẹ si igi kedari ti o wà ni Lebanoni, wipe, Fi ọmọbinrin rẹ fun ọmọ mi li aya: ẹranko igbẹ kan ti o wà ni Lebanoni si kọja nibẹ, o si tẹ ẹ̀gun-ọ̀gan na mọlẹ.
19 Iwọ wipe, Kiyesi i, iwọ ti pa awọn ara Edomu; ọkàn rẹ si gbé soke lati ma ṣogo: njẹ gbe ile rẹ, ẽṣe ti iwọ nfiran fun ifarapa rẹ, ti iwọ o fi ṣubu, ani iwọ ati Juda pẹlu rẹ?
20 Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́; nitori lati ọdọ Ọlọrun wá ni, ki o le fi wọn le awọn ọta wọn lọwọ, nitoriti nwọn nwá awọn oriṣa Edomu.
21 Bẹ̃ni Joaṣi, ọba Israeli gòke lọ; nwọn si wò ara wọn li oju, on ati Amasiah, ọba Juda, ni Bet-Ṣemeṣi ti iṣe ti Juda,
22 A si ṣẹ́ Juda niwaju Israeli, nwọn salọ olukuluku sinu agọ rẹ̀.
23 Joaṣi ọba Israeli si mu Amasiah, ọba Juda ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasiah ni Bet-Ṣemeṣi, o si mu u wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu lati ẹnubode Efraimu titi de ẹnu-bode igun, irinwo igbọnwọ.
24 O si mu gbogbo wura ati fadakà, ati gbogbo ohun-elo ti a ri ni ile Ọlọrun lọdọ Obed-Edomu, ati awọn iṣura ile ọba, ati awọn ògo pẹlu, o si pada lọ si Samaria.
25 Amasiah, ọmọ Joaṣi, ọba Juda, wà li ãye lẹhin ikú Joaṣi, ọmọ Jehoahasi ọba Israeli, li ọdun mẹdogun.
26 Ati iyokù iṣe Amasiah, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kò ha kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli?
27 Njẹ lẹhin àkoko ti Amasiah yipada kuro lati ma tọ̀ Oluwa lẹhin, nwọn di ọ̀tẹ si i ni Jerusalemu; o si salọ si Lakiṣi: ṣugbọn nwọn ranṣẹ tẹlẽ ni Lakiṣi, nwọn si pa a nibẹ.
28 Nwọn si mu u wá lori ẹṣin, nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi.