1 NIGBATI ayaba Ṣeba gbọ́ òkiki Solomoni, o wá lati fi àlọ dan Solomoni wò ni Jerusalemu, pẹlu ẹgbẹ́ nlanla, ati ibakasiẹ ti o ru turari, ati wura li ọ̀pọlọpọ ati okuta iyebiye; nigbati o si de ọdọ Solomoni, o ba a sọ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.
2 Solomoni si dahùn gbogbo ibère rẹ̀: kò si si ohun kan ti o pamọ fun Solomoni ti kò sọ fun u,
3 Nigbati ayaba Ṣeba si ti ri ọgbọ́n Solomoni, ati ile ti o ti kọ́,
4 Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati aṣọ-wiwọ̀ wọn; ati awọn agbọti rẹ̀ pẹlu aṣọ-wiwọ̀ wọn, ati àtẹgun ti o mba gòke lọ si ile Oluwa; kò si kù agbara kan ninu rẹ̀ mọ.
5 O si wi fun ọba pe, otitọ ni ọ̀rọ ti mo gbọ́ ni ilẹ mi niti iṣe rẹ, ati ọgbọ́n rẹ:
6 Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ wọn gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri i; si kiyesi i, a kò rò idaji titobi ọgbọ́n rẹ fun mi; nitori ti iwọ kọja òkiki ti mo ti gbọ́.
7 Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún si ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro nigbagbogbo niwaju rẹ, ti o si ngbọ́ ọgbọ́n rẹ.
8 Olubukún li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o fẹran rẹ lati gbé ọ ka ori itẹ́ rẹ̀ lati ṣe ọba fun Oluwa Ọlọrun rẹ: nitoriti Ọlọrun rẹ fẹran Israeli lati fi idi wọn kalẹ lailai, nitorina ni o ṣe fi ọ jọba lori wọn, lati ṣe idajọ ati otitọ.
9 O si fun ọba li ọgọfa talenti wura, ati turari lọpọlọpọ, ati okuta iyebiye: bẹ̃ni kò ti isi iru turari gẹgẹ bi eyiti ayaba Ṣeba fun Solomoni ọba.
10 Awọn iranṣẹ Huramu pẹlu, ati awọn iranṣẹ Solomoni ti o mu wura Ofiri wá, si mu igi-algumu, ati okuta iyebiye wá pẹlu.
11 Ọba si fi igi-algumu na ṣe àtẹgun ni ile Oluwa, ati ni ile ọba, ati duru ati ohun ọ̀na-orin fun awọn akọrin: a kò si ri iru bẹ̃ ri ni ilẹ Juda.
12 Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba li ohun gbogbo ti o wù u, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti o mu wa fun ọba. Bẹ̃ni o yipada, o si lọ si ilẹ rẹ̀, ati on ati awọn iranṣẹ rẹ̀.
13 Njẹ nisisiyi ìwọn wura ti o de fun Solomoni li ọdun kan ni ọtalelẹgbẹta o le mẹfa talenti wura.
14 Laika eyiti awọn oniṣowo ati awọn èro mu wá. Ati awọn ọba Arabia, ati awọn bãlẹ ilẹ na nmu wura ati fadakà tọ̀ Solomoni wá.
15 Solomoni ọba si ṣe igba asà wura lilù: asà kan gba ẹgbẹta ṣekeli wura lilù.
16 Ọdunrun apata wura lilù li o si ṣe; apata kan gbà ọ̃dunrun ṣekeli wura: ọba si fi wọn sinu ile igbo Lebanoni.
17 Ọba si ṣe itẹ́ ehin-erin nla kan, o si fi wura daradara bò o.
18 Àtẹgun mẹfa ni itẹ́ na ni, pẹlu apoti-itisẹ wura kan, ti a dè mọ itẹ́ na, ati irọpa ni iha mejeji ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba awọn irọpa na.
19 Kiniun mejila si duro lori atẹgun mẹfẹfa na, ni iha ekini ati ni iha ekeji. A kò ṣe iru rẹ̀ ri ni gbogbo ijọba.
20 Ati gbogbo ohun-elo mimu Solomoni ọba jẹ wura, ati gbogbo ohun-elo ile igbo Lebanoni, wura daradara ni: kò si ti fadakà; a kò kà fadakà si nkankan li ọjọ Solomoni.
21 Nitori awọn ọkọ̀ ọba nlọ si Tarṣiṣi pẹlu awọn iranṣẹ Huramu; ẹ̃kan li ọdun mẹta li awọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ide, nwọn nmu wura, ati fadakà, ati ehin-erin, ati inaki, ati ẹiyẹ-ologe wá.
22 Solomoni ọba si tobi jù gbogbo ọba aiye lọ li ọrọ̀ ati li ọgbọn.
23 Gbogbo awọn ọba aiye si nwá oju Solomoni, lati gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀ ti Ọlọrun ti fi si i li ọkàn.
24 Olukuluku si mu ọrẹ tirẹ̀ wá, ohun-elo fadakà ati ohun-elo wura, ati aṣọ ibora, ihamọra, ati turari, ẹṣin, ati ibaka, iye kan li ọdọdun.
25 Solomoni si ni ẹgbaji ile fun ẹṣin ati kẹkẹ́, ati ẹgbafa ẹlẹṣin, ti o fi si awọn ilu kẹkẹ́, ati ọdọ ọba ni Jerusalemu.
26 O si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò (Euferate) titi de ilẹ awọn ara Filistia ati de àgbegbe Egipti.
27 Ọba si sọ fadakà dabi okuta ni Jerusalemu, ati igi-kedari li o si ṣe bi sikamore, ti o wà ni pẹtẹlẹ li ọ̀pọlọpọ.
28 Nwon si mu ẹṣin tọ̀ Solomoni lati Egipti wá, ati lati ilẹ gbogbo.
29 Ati iyokù iṣe Solomoni ti iṣaju ati ti ikẹhin, a kọ ha kọ wọn sinu iwe Natani woli, ati sinu asọtẹlẹ Ahijah, ara Ṣilo, ati sinu iran Iddo, ariran, sipa Jeroboamu, ọmọ Nebati.
30 Solomoni si jọba ni Jerusalemu lori gbogbo Israeli li ogoji ọdun.
31 Solomoni si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi baba rẹ̀: Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.