2. Kro 34 YCE

Josaya, Ọba Juda

1 ẸNI ọdun mẹjọ, ni Josiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanlelọgbọn ni Jerusalemu.

2 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, o si rìn li ọ̀na Dafidi, baba rẹ̀, kò si yà si ọwọ ọtún tabi si òsi.

Josaya Gbógun ti Ìwà Ìbọ̀rìṣà

3 Nitori li ọdun kẹjọ ijọba rẹ̀, nigbati o si wà li ọdọmọde sibẹ, o bẹ̀rẹ si iwá Ọlọrun Dafidi, baba rẹ̀; ati li ọdun kejila, o bẹ̀rẹ si iwẹ̀ Juda ati Jerusalemu mọ́ kuro ninu ibi giga wọnni, ati ere-oriṣa, ati ere yiyá, ati ere didà.

4 Nwọn si wó pẹpẹ Baalimu lulẹ niwaju rẹ̀; ati awọn ere õrun ti o wà lori wọn li o ké lulẹ; ati awọn ere-oriṣa, ati awọn ere yiyá, ati awọn ere didà, li o fọ tũtu, o sọ wọn di ekuru, o si gbọ̀n ọ sori isa-okú awọn ti o ti nrubọ́ si wọn.

5 O si sun egungun awọn alufa-oriṣa lori pẹpẹ wọn; o si wẹ Juda ati Jerusàlemu mọ́.

6 Bẹ̃li o si ṣe ni ilu Manasse wọnni ati ti Efraimu, ati ti Simeoni, ani titi de Naftali, o tú ile wọn yikakiri.

7 Nigbati o si fọ́ awọn pẹpẹ ati ère-oriṣa dilẹ, ti o si ti gún awọn ere yiyá di ẹ̀tu, ti o si ti ké gbogbo awọn ère-õrun lulẹ ni gbogbo ilẹ Israeli, o pada si Jerusalemu.

Wọ́n Rí Ìwé Òfin

8 Njẹ li ọdun kejidilogun ijọba rẹ̀, nigbati o ti wẹ̀ ilẹ na mọ́, ati ile na, o rán Ṣafani, ọmọ Asaliah, ati Maaseiah, olori ilu na, ati Joa, ọmọ Joahasi, akọwe iranti, lati tun ile Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ṣe.

9 Nigbati nwọn si de ọdọ Hilkiah, olori alufa, nwọn fi owo na ti a mu wá sinu ile Ọlọrun le e lọwọ, ti awọn ọmọ Lefi, ti o ntọju ilẹkun, ti kójọ lati ọwọ Manasse ati Efraimu, ati lati ọdọ gbogbo awọn iyokù Israeli, ati lati gbogbo Juda ati Benjamini: nwọn si pada si Jerusalemu.

10 Nwọn si fi i le ọwọ awọn ti nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto iṣẹ ile Oluwa, nwọn si fi i fun awọn aṣiṣẹ ti nṣiṣẹ ile Oluwa, lati tun ile na ṣe:

11 Awọn ọlọnà ati awọn kọlekọle ni nwọn fifun lati ra okuta gbigbẹ́, ati ìti-igi fun isopọ̀, ati lati tẹ́ ile wọnni ti awọn ọba Juda ti bajẹ.

12 Awọn ọkunrin na fi otitọ ṣiṣẹ na: awọn alabojuto wọn ni Jahati ati Obadiah, awọn ọmọ Lefi, ninu awọn ọmọ Merari; ati Sekariah ati Meṣullamu, ninu awọn ọmọ Kohati, lati mu iṣẹ lọ; ati gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o ni ọgbọ́n ohun-elo orin.

13 Nwọn si wà lori awọn alãru, ati awọn alabojuto gbogbo awọn ti nṣiṣẹ, ninu ìsinkisin ati ninu awọn ọmọ Lefi ni akọwe, ati olutọju ati adèna.

14 Nigbati nwọn si mu owo na ti a mu wá sinu ile Oluwa jade wá, Hilkiah alufa, ri iwe ofin Oluwa ti a ti ọwọ Mose kọ.

15 Hilkiah si dahùn o si wi fun Ṣafani, akọwe, pe, Emi ri iwe ofin ninu ile Oluwa, Hilkiah si fi iwe na le Ṣafani lọwọ.

16 Ṣafani si mu iwe na tọ̀ ọba lọ, o si mu èsi pada fun ọba wá wipe, Gbogbo eyi ti a fi le awọn iranṣẹ rẹ lọwọ, nwọn ṣe e.

17 Nwọn si ti kó gbogbo owo ti a ri ni ile Oluwa jọ, nwọn si ti fi le ọwọ awọn alabojuto, ati le ọwọ awọn ti nṣiṣẹ.

18 Nigbana ni Ṣafani, akọwe, wi fun ọba pe, Hilkiah alufa, fun mi ni iwe kan. Ṣafani si kà a niwaju ọba.

19 O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ ofin na, o si fa aṣọ rẹ̀ ya.

20 Ọba si paṣẹ fun Hilkiah ati Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Abdoni, ọmọ Mika, ati Ṣafani, akọwe, ati Asaiah, iranṣẹ ọba, wipe,

21 Ẹ lọ, ẹ bere lọwọ Oluwa fun mi, ati fun awọn ti o kù ni Israeli ati ni Juda, niti ọ̀rọ iwe ti a ri: nitori titobi ni ibinu Oluwa ti a tú jade sori wa, nítori awọn bàba wa kò pa ọ̀rọ Oluwa mọ́, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu iwe yi.

22 Ati Hilkiah, ati awọn ti ọba ti yàn tọ̀ Hulda, woli obinrin, lọ, aya Ṣallumu, ọmọ Tikehati, ọmọ Hasra, olutọju aṣọ (njẹ, o ngbe Jerusalemu, niha keji;) nwọn si ba a sọ̀rọ na.

23 O si dá wọn lohùn pe, Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi, Ẹ sọ fun ọkunrin na ti o rán nyin si mi pe,

24 Bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o mu ibi wá si ihinyi ati si awọn ti ngbe ibẹ na, ani gbogbo egún ti a kọ sinu iwe ti nwọn ti kà niwaju ọba Juda:

25 Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti sun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina li a o ṣe tú ibinu mi sori ihinyi, a kì yio si paná rẹ̀.

26 Bi o si ṣe ti ọba Juda nì, ẹniti o rán nyin lati bère lọwọ Oluwa, Bayi ni ki ẹnyin ki o wi fun u, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi niti ọ̀rọ wọnni ti iwọ ti gbọ́:

27 Nitoriti ọkàn rẹ rọ̀, ti iwọ si rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun, nigbati iwọ gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ si ihinyi, ati si awọn ti ngbe ibẹ, ti iwọ si rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju mi, ti iwọ si fa aṣọ rẹ ya, ti iwọ si sọkun niwaju mi; ani emi ti gbọ́ tirẹ pẹlu, li Oluwa wi.

28 Kiyesi i, emi o kó ọ jọ sọdọ awọn baba rẹ, a o si kó ọ jọ si isa-okú rẹ li alafia, bẹ̃ni oju rẹ kì yio ri gbogbo ibi ti emi o mu wá si ihinyi, ati sori awọn ti ngbe ibẹ. Bẹ̃ni nwọn mu èsi pada fun ọba wá.

Josaya Dá Majẹmu láti Tẹ̀lé OLUWA

29 Nigbana ni ọba ranṣẹ, nwọn si kó gbogbo awọn àgba Juda ati Jerusalemu jọ.

30 Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo ọkunrin Juda, ati awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo enia ati ẹni-nla ati ẹni-kekere: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn.

31 Ọba si duro ni ipò rẹ̀, o si dá majẹmu niwaju Oluwa lati ma fi gbogbo aiya ati gbogbo ọkàn rìn tọ̀ Oluwa lẹhin, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati ẹri rẹ̀, ati aṣẹ rẹ̀, lati ṣe ọ̀rọ majẹmu na ti a kọ sinu iwe yi.

32 O si mu ki gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalemu ati Benjamini duro ninu rẹ̀, awọn ti ngbe Jerusalemu si ṣe gẹgẹ bi majẹmu Ọlọrun, Ọlọrun awọn baba wọn.

33 Josiah si kó gbogbo ohun-irira kuro ninu gbogbo ilu ti iṣe ti awọn ọmọ Israeli, o si mu ki gbogbo awọn ti o wà ni Israeli ki o sìn, ani ki nwọn sìn Oluwa Ọlọrun wọn. Ati li ọjọ rẹ̀ gbogbo nwọn kò yà kuro lati ma tọ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn, lẹhin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36