1 JEHOṢAFATI si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Jehoramu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
2 O si ni awọn arakunrin, awọn ọmọ Jehoṣafati, Asariah, ati Jehieli, ati Sekariah, ati Asariah ati Mikaeli, ati Ṣefatiah: gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Jehoṣafati, ọba Juda.
3 Baba wọn si bun wọn li ẹ̀bun pupọ, ni fadakà ati ni wura, ati ohun iyebiye, pẹlu ilu olodi ni Juda, ṣugbọn o fi ijọba fun Jehoramu: nitori on li akọbi.
4 Nigbati Jehoramu si dide si ijọba baba rẹ̀, o mu ara rẹ̀ le, o si fi idà pa gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati ninu awọn ijoye Israeli.
5 Jehoramu jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọ̀n nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mẹjọ ni Jerusalemu.
6 O si rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, gẹgẹ bi ile Ahabu ti ṣe: nitoriti o ni ọmọbinrin Ahabu li aya: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa.
7 Ṣugbọn Oluwa kò fẹ ipa ile Dafidi run, nitori majẹmu ti o ti ba Dafidi da, ati bi o ti ṣe ileri lati fun u ni imọlẹ kan ati fun awọn ọmọ rẹ̀ lailai.
8 Li ọjọ rẹ̀ li awọn ara Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda, nwọn si jẹ ọba fun ara wọn.
9 Nigbana ni Jehoramu rekọja lọ pẹlu awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o ká a mọ, ati awọn olori kẹkẹ́.
10 Sibẹ awọn ara Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda, titi di oni yi. Akokò na pẹlu ni Libna ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ rẹ̀; nitoriti o ti kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ.
11 Pẹlupẹlu o ṣe ibi giga wọnni lori òke Judah, o si mu ki awọn olugbe Jerusalemu ki o ṣe àgbere, o si mu Juda ṣẹ̀.
12 Iwe kan si ti ọdọ Elijah, woli, wá si ọdọ rẹ̀ wipe: Bayi li Oluwa, Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi, nitoriti iwọ kò rìn li ọ̀na Jehoṣafati, baba rẹ, tabi li ọ̀na Asa, ọba Juda;
13 Ṣugbọn ti iwọ rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, iwọ si ti mu Juda ati awọn olugbe Jerusalemu tọ ọ̀na panṣaga, gẹgẹ bi panṣaga ile Ahabu, ati ti iwọ si pa awọn arakunrin ile baba rẹ ti o jẹ ẹni-rere jù iwọ lọ:
14 Kiyesi i, Oluwa yio fi àjakalẹ-arun nla kọlù awọn enia rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn obinrin rẹ, ati gbogbo ọrọ̀ rẹ:
15 Iwọ o ṣe aisan pupọ, àrun nla ninu ifun rẹ, titi ifun rẹ yio fi tu jade nitori àrun ọjọ pupọ.
16 Pẹlupẹlu, Oluwa ru ẹmi awọn ara Filistia, ati ti awọn ara Arabia, ti o sunmọ awọn ara Etiopia, soke si Jehoramu.
17 Nwọn si gòke wá si Juda, nwọn si ya wọle, nwọn si kó gbogbo ọrọ̀ ti a ri ni ile ọba ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, ati awọn obinrin rẹ̀, ni igbekun lọ; tobẹ̃ ti a kò ṣẹ́ku ọkunrin kan silẹ fun u, bikòṣe Jehoahasi, abikẹhin ninu awọn ọmọ rẹ̀.
18 Lẹhin gbogbo eyi Oluwa fi àrun, ti a kò le wòsan, kọlù u ni ifun.
19 O si ṣe bẹ̃ bi akokò ti nlọ ati lẹhin ọdun meji, ni ifun rẹ̀ tu jade nitori aìsan rẹ̀, o si kú ninu irora buburu na: awọn enia rẹ̀ kò si ṣe ijona fun u gẹgẹ bi ijona ti awọn baba rẹ̀.
20 Ẹni ọdun mejilelọgbọn ni nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹjọ ni Jerusalemu, o si fi ilẹ silẹ laiwu ni: nwọn si sìn i ni ilu Dafidi; ṣugbọn kì iṣe ninu iboji awọn ọba.