2. Kro 13 YCE

Ogun láàrin Abija ati Jeroboamu

1 LI ọdun kejidilogun Jeroboamu, ọba, ni Abijah bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda.

2 O jọba li ọdun mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Mikaiah ọmọbinrin Urieli ti Gibea, ọtẹ si wà lãrin Abijah ati Jeroboamu.

3 Abijah si fi awọn alagbara akọni ologun dì ogun na, ani ogún ọkẹ́ enia ti a yàn, Jeroboamu pẹlu si fi ogoji ọkẹ enia ti a yàn, awọn alagbara akọni enia tẹ́ ogun si i.

4 Abijah si duro lori oke Semaraimu, ti o wà li òke Efraimu, o si wipe, Ẹ gbọ́ temi, Jeroboamu ati gbogbo Israeli!

5 Kò ha tọ́ ki ẹnyin ki o mọ̀ pe: Oluwa Ọlọrun Israeli fi ijọba lori Israeli fun Dafidi lailai, ani fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa majẹmu iyọ̀?

6 Jeroboamu, ọmọ Nebati, iranṣẹ Solomoni, ọmọ Dafidi dide, o si ṣọ̀tẹ si oluwa rẹ̀.

7 Awọn enia lasan si ko ara wọn jọ si ọdọ rẹ̀, awọn ọmọ ẹni buburu, nwọn si mu ara wọn le si Rehoboamu, ọmọ Solomoni, nigbati Rehoboamu wà li ọdọmọde ti inu rẹ̀ si rọ̀, ti kò si le kò wọn loju.

8 Ati nisisiyi ẹnyin rò lati kò ijọba Oluwa loju li ọwọ ọmọ Dafidi; ọ̀pọlọpọ si li ẹnyin, ati pẹlu nyin awọn ẹgbọrọmalu wura ti Jeroboamu ṣe li ọlọrun fun nyin.

9 Ẹnyin kò ha ti lé awọn alufa Oluwa jade, awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi, ẹnyin si ti ṣe awọn alufa fun ara nyin, gẹgẹ bi iṣe awọn orilẹ-ède ilẹ miran? bẹ̃ni ẹnikẹni ti o ba wá, ti ọwọ rẹ kún pẹlu ọdọ-akọ-malu ati àgbo meje, on na le ma ṣe alufa awọn ti kì iṣe ọlọrun.

10 Ṣugbọn bi o ṣe ti wa ni, Oluwa li Ọlọrun wa, awa kò si kọ̀ ọ silẹ ati awọn alufa, ti nṣe iranṣẹ fun Oluwa, ani awọn ọmọ Aaroni ati awọn ọmọ Lefi ninu iṣẹ wọn.

11 Nwọn si nsun ọrẹ-ẹbọ sisun ati turari didùn li orowurọ ati li alalẹ si Oluwa: àkara ifihan pẹlu ni nwọn si ntò lori tabili mimọ́; ati ọpa fitila wura pẹlu fitila wọn, lati ma jó lalalẹ; nitori ti awa npa aṣẹ Oluwa Ọlọrun wa mọ́; ṣugbọn ẹnyin kọ̀ ọ silẹ.

12 Si kiyesi i, Ọlọrun tikararẹ̀ si wà pẹlu wa li Olori wa, ati awọn alufa rẹ̀ pẹlu ipè didún ijaiya lati dún si nyin, Ẹnyin ọmọ Israeli, ẹ máṣe ba Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin jà; nitori ẹ kì yio ṣe rere.

13 Ṣugbọn Jeroboamu mu ki ogun-ẹ̀hin ki o bù wọn li ẹhin: bẹ̃ni nwọn mbẹ niwaju Juda, ati ogun-ẹhin na si mbẹ lẹhin wọn.

14 Nigbati Juda si bojuwo ẹhin, si kiyesi i, ogun mbẹ niwaju ati lẹhin: nwọn si ke pè Oluwa, awọn alufa si fún ipè.

15 Olukuluku, ọkunrin Juda si hó: o si ṣe, bi awọn ọkunrin Juda si ti hó, ni Ọlọrun kọlu Jeroboamu ati gbogbo Israeli niwaju Abijah ati Juda.

16 Awọn ọmọ Israeli si sa niwaju Juda: Ọlọrun si fi wọn le wọn lọwọ.

17 Abijah ati awọn enia rẹ̀ si pa ninu wọn li ọ̀pọlọpọ: bẹ̃ni ọkẹ mẹdọgbọn ọkunrin ti a yàn ṣubu ni pipa ninu Israeli.

18 Bayi li a rẹ̀ awọn ọmọ Israeli silẹ li akoko na, awọn ọmọ Juda si bori nitori ti nwọn gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn.

19 Abijah si lepa Jeroboamu, o si gbà ilu lọwọ rẹ̀, Beteli pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Jeṣana pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Efraimu pẹlu awọn ilu rẹ̀.

20 Bẹ̃ni Jeroboamu kò si tun li agbara mọ li ọjọ Abijah: Oluwa si lù u, o si kú.

21 Abijah si di alagbara, o si gbe obinrin mẹtala ni iyawo, o si bi ọmọkunrin mejilelogun, ati ọmọbinrin mẹrindilogun.

22 Ati iyokù iṣe Abijah, ati iwà rẹ̀, ati iṣẹ rẹ̀, a kọ wọn sinu iwe-itumọ Iddo, woli.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36