1 ẸNI ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni Jotamu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jeruṣa, ọmọbinrin Sadoku.
2 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe; kiki kò wọ inu tempili Oluwa lọ, ṣugbọn awọn enia nṣe ibi sibẹsibẹ.
3 On si kọ́ ẹnu-ọ̀na giga ile Oluwa, ati lori odi Ofeli, o kọ́ pupọ.
4 Ani o kọ́ ilu wọnni li òke Juda, ati ninu igbo, o mọ ile-odi ati ile-iṣọ.
5 O si ba ọba awọn ara Ammoni jà pẹlu, o si bori wọn. Awọn ara Ammoni si fun u li ọgọrun talenti fadakà li ọdun na, ati ẹgbãrun oṣuwọn alikama, ati ẹgbãrun ti barli. Eyi li awọn ara Ammoni san fun u, ati lọdun keji ati lọdun kẹta.
6 Bẹ̃ni Jotamu di alagbara, nitoriti o tun ọ̀na rẹ̀ ṣe niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ̀.
7 Ati iyokù iṣe Jotamu ati gbogbo ogun rẹ̀, ati ọ̀na rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Juda.
8 Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu.
9 Jotamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu Dafidi: Ahasi, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.