1 LI ọdun kẹrindilogoji ijọba Asa, Baaṣa, ọba Israeli, gòke wá si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má ba jẹ ki ẹnikan ki o jade, tabi ki o wọle tọ̀ Asa, ọba Juda lọ.
2 Nigbana ni Asa mu fadakà ati wura jade lati inu iṣura ile Oluwa wá, ati ile ọba, o si ranṣẹ si Benhadadi, ọba Siria, ti ngbe Damasku, wipe,
3 Majẹmu kan wà larin temi tirẹ, bi o ti wà lãrin baba mi ati baba rẹ; kiyesi i, mo fi fadakà ati wura ranṣẹ si ọ; lọ, bà majẹmu ti o ba Baaṣa, ọba Israeli dá jẹ, ki o le lọ kuro lọdọ mi.
4 Benhadadi si gbọ́ ti Asa ọba, o si rán awọn olori ogun rẹ̀ si ilu Israeli wọnni, nwọn si kọlù Ijoni, ati Dani, ati Abel-Maimu, ati gbogbo ilu iṣura Naftali.
5 O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o ṣiwọ atikọ́ Rama, o si dá iṣẹ rẹ̀ duro.
6 Ṣugbọn Asa ọba kó gbogbo Juda jọ; nwọn si kó okuta ati igi Rama lọ, eyiti Baaṣa nfi kọ́le; o si fi kọ́ Geba ati Mispa.
7 Li àkoko na Hanani, ariran, wá sọdọ Asa, ọba Juda, o si wi fun u pe, Nitoriti iwọ gbẹkẹle ọba Siria, iwọ kò si gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun rẹ, nitorina ni ogun ọba Siria ṣe bọ́ lọwọ rẹ.
8 Awọn ara Etiopia ati awọn ara Libia kì iha ise ogun nla, pẹlu ọ̀pọlọpọ kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin? ṣugbọn nitoriti iwọ gbẹkẹle Oluwa, on fi wọn le ọ lọwọ.
9 Nitoriti oju Oluwa nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pípe si ọdọ rẹ̀. Ninu eyi ni iwọ hùwa aṣiwere: nitorina lati isisiyi lọ ogun yio ma ba ọ jà.
10 Asa si binu si ariran na, o si fi i sinu tubu; nitoriti o binu si i niti eyi na. Asa si ni ninu awọn enia na lara li akokò na.
11 Si kiyesi i, iṣe Asa ti iṣaju ati ti ikẹhin, wò o, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli.
12 Ati li ọdun kọkandilogoji ijọba rẹ̀, Asa ṣe aisan li ẹsẹ rẹ̀, titi àrun rẹ̀ fi pọ̀ gidigidi: sibẹ ninu aisan rẹ̀ on kò wá Oluwa, bikòṣe awọn oniṣegun.
13 Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, o si kú li ọdun kọkanlelogoji ijọba rẹ̀.
14 Nwọn si sìn i sinu isa-okú, ti o gbẹ́ fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, nwọn si tẹ́ ẹ lori àkete ti a fi õrun-didùn kùn, ati oniruru turari ti a fi ọgbọ́n awọn alapolu pèse: nwọn si ṣe ijona nlanla fun u.