1 BI Solomoni si ti pari adura igbà, iná bọ́ lati ọrun wá, o si jo ọrẹ sisun ati ẹbọ na run; ogo Oluwa si kún ile na.
2 Awọn alufa kò le wọ̀ inu ile Oluwa, nitori ogo Oluwa kún ile Oluwa.
3 Gbogbo awọn ọmọ Israeli si ri bi iná na ti bọ́ silẹ, ati ogo Oluwa sori ile na, nwọn doju wọn bò ilẹ ti a fi okuta tẹ́, nwọn si tẹriba, nwọn si yìn Oluwa, wipe, Nitoriti o ṣeun; nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.
4 Ọba ati awọn enia si rubọ niwaju Oluwa.
5 Solomoni ọba si rubọ ẹgbã-mọkanla malu ati ọkẹ mẹfa agutan: bẹ̃ni ọba, ati gbogbo awọn enia yà ile Ọlọrun na si mimọ́.
6 Awọn alufa duro lẹnu iṣẹ wọn; awọn ọmọ Lefi pẹlu ohun-ọnà orin Oluwa, ti Dafidi ọba ti ṣe lati yìn Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai, nigbati Dafidi nkọrin iyìn nipa ọwọ wọn; awọn alufa si fùn ipè niwaju wọn, gbogbo Israeli si dide duro.
7 Solomoni si yà arin agbala na si mimọ́ ti mbẹ niwaju ile Oluwa: nitori nibẹ li o ru ẹbọ ọrẹ sisun, ati ọra ẹbọ alafia, nitori pẹpẹ idẹ ti Solomoni ti ṣe kò le gbà ọrẹ sisun, ati ọrẹ onjẹ ati ọ̀ra na.
8 Li akokò na pẹlu Solomoni se àse na ni ijọ meje, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ijọ enia nlanla, lati ìwọ Hamati titi de odò Egipti.
9 Ati li ọjọ kẹjọ nwọn ṣe apejọ mimọ́; nitori ti nwọn ṣe ìyasi-mimọ́ pẹpẹ na li ọjọ meje, ati àse na, ọjọ meje.
10 Ati li ọjọ kẹtalelogun oṣù keje, o rán awọn enia pada lọ sinu agọ wọn, pẹlu ayọ̀ ati inudidùn nitori ore-ọfẹ ti Oluwa ti fi hàn fun Dafidi, ati fun Solomoni, ati fun Israeli, enia rẹ̀.
11 Solomoni si pari ile Oluwa, ati ile ọba, ati gbogbo ohun ti o wá si ọkàn Solomoni lati ṣe ninu ile Oluwa, ati ninu ile on tikararẹ̀, o si ṣe e jalẹ.
12 Oluwa si fi ara hàn Solomoni li oru, o si wi fun u pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti yàn ihinyi fun ara mi, fun ile ẹbọ.
13 Bi mo ba sé ọrun ti kò ba si òjo, tabi bi emi ba paṣẹ fun eṣú lati jẹ ilẹ na run, tabi bi mo ba rán àjakalẹ-arun si ãrin awọn enia mi;
14 Bi awọn enia mi ti a npè orukọ mi mọ́, ba rẹ̀ ara wọn silẹ, ti nwọn ba si gbadura, ti nwọn ba si wá oju mi, ti nwọn ba si yipada kuro ninu ọ̀na buburu wọn; nigbana ni emi o gbọ́ lati ọrun wá, emi o si dari ẹ̀ṣẹ wọn jì, emi o si wò ilẹ wọn sàn.
15 Nisisiyi oju mi yio ṣí, eti mi yio si tẹ́ si adura ibi yi.
16 Njẹ nisisiyi emi ti yàn, emi si ti yà ile yi si mimọ́, ki orukọ mi ki o le ma wà nibẹ lailai: ati oju mi ati ọkàn mi yio ma wà nibẹ nigbagbogbo.
17 Ati iwọ, bi iwọ o ba rìn niwaju mi bi Dafidi, baba rẹ ti rìn, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, bi iwọ o ba si ṣe akiyesi aṣẹ mi ati idajọ mi;
18 Nigbana ni emi o fi idi itẹ ijọba rẹ múlẹ̀, gẹgẹ bi emi ti ba Dafidi, baba rẹ dá majẹmu, wipe, a kì yio fẹ ẹnikan kù fun ọ ti yio ma ṣe akoso ni Israeli.
19 Ṣugbọn bi ẹnyin ba yipada, ti ẹ ba si kọ̀ aṣẹ mi ati ofin mi silẹ, ti emi ti gbé kalẹ niwaju nyin, ti ẹnyin ba si sin ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn;
20 Nigbana ni emi o fà wọn tu ti-gbongbo-ti-gbongbo kuro ni ilẹ ti emi ti fi fun wọn; ati ile yi, ti emi ti yà si mimọ́ fun orukọ mi, li emi o ta nù kuro niwaju mi, emi o si sọ ọ di owe, ati ọ̀rọ-ẹgan larin gbogbo orilẹ-ède.
21 Ati ile yi, ti o ga, yio di ohun iyanu fun gbogbo ẹni ti o gba ibẹ kọja; tobẹ̃ ti yio si wipe, ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi, ati si ile yi?
22 A o si dahùn wipe, Nitori ti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, Ẹniti o mu wọn ti ilẹ Egipti jade wá, ti nwọn si di ọlọrun miran mu, ti nwọn si bọ wọn, ti nwọn si sìn wọn: nitorina li o ṣe mu gbogbo ibi yi ba wọn.