1 O si ṣe, nigbati Rehoboamu ti fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ ti o si ti mu ara rẹ̀ le, o kọ̀ ofin Oluwa silẹ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀.
2 O si ṣe ni ọdun karun Rehoboamu ọba, ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, gòke wá si Jerusalemu, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si Oluwa.
3 Pẹlu ẹgbẹfa kẹkẹ́, ati ọkẹ́ mẹta ẹlẹṣin: awọn enia ti o ba a ti Egipti wá kò niye; awọn ara Libia, awọn ara Sukki, ati awọn ara Etiopia.
4 O si kọ́ awọn ilu olodi ti iṣe ti Juda, o si wá si Jerusalemu.
5 Nigbana ni Ṣemaiah, woli, tọ̀ Rehoboamu wá, ati awọn ijoye Juda, ti o kojọ pọ̀ si Jerusalemu nitori Ṣiṣaki, o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi, enyin ti kọ̀ mi silẹ, nitorina li emi si ṣe fi nyin silẹ si ọwọ Ṣiṣaki.
6 Nigbana li awọn ijoye Israeli ati ọba rẹ̀ ara wọn silẹ; nwọn si wipe: Oluwa li olododo!
7 Nigbati Oluwa ri pe nwọn rẹ̀ ara wọn silẹ, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Ṣemaiah wá, wipe, Nwọn ti rẹ̀ ara wọn silẹ; nitorina emi kì o run wọn, ṣugbọn emi o fun wọn ni igbala diẹ: a kì yio dà ibinu mi sori Jerusalemu nipa ọwọ Ṣiṣaki.
8 Ṣugbọn nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ̀: ki nwọn ki o le mọ̀ ìsin mi, ati ìsin ijọba ilẹ wọnni.
9 Bẹ̃ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, goke wá si Jerusalemu, o si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; o kó gbogbo rẹ̀: o kó awọn asà wura lọ pẹlu ti Solomoni ti ṣe.
10 Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn le ọwọ olori ẹṣọ ti ntọju ọ̀na ile ọba.
11 O si ṣe, nigbakugba ti ọba ba si wọ̀ ile Oluwa lọ, awọn ẹṣọ a de, nwọn a si kó wọn wá, nwọn a si kó wọn pada sinu iyara ẹṣọ.
12 Nigbati o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ibinu Oluwa yipada kuro lọdọ rẹ̀, ti kò fi run u patapata: ni Juda pẹlu, ohun rere si mbẹ.
13 Bẹ̃ni Rehoboamu ọba mu ara rẹ̀ le ni Jerusalemu, o si jọba: nitori Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mẹtadinlogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni.
14 O si ṣe buburu, nitori ti kò mura ọkàn rẹ̀ lati wá Oluwa.
15 Njẹ iṣe Rehoboamu, ti iṣaju ati ti ikẹhin, a kò ha kọ wọn sinu iwe Ṣemaiah, woli, ati ti Iddo, ariran, nipa iwe itan idile? Ọtẹ si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu nigbagbogbo.
16 Rehoboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi: Abijah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.