1 ẸNI ogun ọdun ni Ahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu: on kò si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀:
2 Nitoriti o rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, o si ṣe ere didà fun Baalimu pẹlu.
3 O si sun turari li àfonifoji ọmọ Hinnomu, o si sun awọn ọmọ rẹ̀ ninu iná bi ohun-irira awọn orilẹ-ède, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.
4 O si rubọ, o si sun turari ni ibi giga wọnni, ati lori òke kekere, ati labẹ gbogbo igi tutu.
5 Nitorina Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fi i le ọba Siria lọwọ; nwọn si kọlù u, nwọn si kó ọ̀pọlọpọ ni igbekun lọ ninu wọn, nwọn si mu wọn wá si Damasku. A si fi i le ọba Israeli lọwọ pẹlu, ti o pa a ni ipakupa.
6 Nitoriti Peka, ọmọ Remaliah, pa ọkẹ mẹfa enia ni Juda ni ijọ kan, gbogbo awọn ọmọ-ogun: nitoriti nwọn ti kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ.
7 Ati Sikri, alagbara kan ni Efraimu, pa Maaseiah, ọmọ ọba, ati Asirkamu, olori ile, ati Elkana, ibikeji ọba.
8 Awọn ọmọ Israeli si kó ọkẹ mẹwa ninu awọn arakunrin wọn ni igbekun lọ, awọn obinrin, awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin, nwọn si kó ikogun pupọ lọdọ wọn pẹlu, nwọn si mu ikogun na wá si Samaria.
9 Woli Oluwa kan si wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Odedi: o si jade lọ ipade ogun ti o wá si Samaria, o si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nitoriti Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin binu si Juda li on ṣe fi wọn le nyin lọwọ, ẹnyin si pa wọn ni ipa-oro ti o de òke ọrun.
10 Ati nisisiyi ẹnyin npete lati tẹ awọn ọmọ Juda ati Jerusalemu ba fun ẹrú-kunrin ati ẹrú-birin nyin: ẹnyin kò ha jẹbi Oluwa Ọlọrun nyin, ani ẹnyin?
11 Njẹ nitorina, ẹ gbọ́ temi, ki ẹ si jọwọ awọn igbekun ti ẹnyin ti kó ni igbekun ninu awọn arakunrin nyin lọwọ lọ: nitori ibinu kikan Oluwa mbẹ lori nyin.
12 Nigbana li awọn kan ninu awọn olori, awọn ọmọ Efraimu, Asariah, ọmọ Johanani, Berekiah, ọmọ Meṣillemoti, ati Jehiskiah, ọmọ Ṣallumu, ati Amasa, ọmọ Hadlai, dide si awọn ti o ti ogun na bọ̀.
13 Nwọn si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò gbọdọ mu awọn igbekun nì wá ihin: nitori wò o, awa ti jẹbi niwaju Oluwa, ẹnyin npete ati fi kún ẹ̀ṣẹ ati ẹbi wa: ẹbi wa sa tobi, ibinu kikan si wà lori Israeli.
14 Bẹ̃li awọn enia ti o hamọra fi awọn igbekun ati ikogun na silẹ niwaju awọn ijoye, ati gbogbo ijọ enia.
15 Awọn ọkunrin ti a pè li orukọ na si dide, nwọn si mu awọn igbekun na, nwọn si fi ikogun na wọ̀ gbogbo awọn ti o wà ni ihoho ninu wọn, nwọn si wọ̀ wọn laṣọ, nwọn si bọ̀ wọn ni bàta, nwọn si fun wọn ni ohun jijẹ ati ohun mimu, nwọn si fi ororo kùn wọn li ara, nwọn si kó gbogbo awọn alailera ninu wọn sori kẹtẹkẹtẹ, nwọn si mu wọn wá si Jeriko, ilu ọlọpẹ si ọdọ arakunrin wọn: nigbana ni nwọn pada wá si Samaria.
16 Li akokò na ni Ahasi ọba, ranṣẹ si awọn ọba Assiria lati ràn on lọwọ.
17 Awọn ara Edomu si tun wá, nwọn si kọlù Juda, nwọn si kó igbekun diẹ lọ.
18 Awọn ara Filistia pẹlu ti gbé ogun lọ si ilu pẹtẹlẹ wọnni, ati siha gusu Juda, nwọn si ti gbà Bet-ṣemeṣi, ati Ajaloni, ati Gederoti, ati Ṣoko pẹlu ileto rẹ̀, Timna pẹlu ileto rẹ̀, ati Gimso pẹlu ati ileto rẹ̀: nwọn si ngbe ibẹ.
19 Nitoriti Oluwa ti rẹ̀ Juda silẹ nitori Ahasi, ọba Juda: nitoriti o mu Juda di alaini iranlọwọ, o si ṣe irekọja gidigidi si Oluwa.
20 Tilgati-pilnesari, ọba Assiria, si tọ̀ ọ wá, ọ si pọn ọ loju, ṣugbọn kò fun u li agbara.
21 Ahasi sa kó ninu ini ile Oluwa, ati ninu ile ọba, ati ti awọn ijoye, o si fi fun ọba Assiria: ṣugbọn kò ràn a lọwọ.
22 Ati li akokò ipọnju rẹ̀, o tun ṣe irekọja si i si Oluwa. Eyi ni Ahasi, ọba.
23 Nitori ti o rubọ si awọn oriṣa Damasku, awọn ẹniti o kọlù u: o si wipe, Nitoriti awọn oriṣa awọn ọba Siria ràn wọn lọwọ, nitorina li emi o rubọ si wọn, ki nwọn le ràn mi lọwọ. Ṣugbọn awọn na ni iparun rẹ̀ ati ti gbogbo Israeli.
24 Ahasi si kó gbogbo ohun-elo ile Ọlọrun jọ, o si ké kuro lara ohun-elo ile Ọlọrun, o si tì ilẹkun ile Oluwa, o si tẹ́ pẹpẹ fun ara rẹ̀ ni gbogbo igun Jerusalemu.
25 Ati ni gbogbo orori ilu Juda li o ṣe ibi giga wọnni, lati sun turari fun awọn ọlọrun miran, o si mu Oluwa Ọlọrun awọn baba rẹ̀ binu.
26 Ati iyokù iṣe rẹ̀, ati ti gbogbo ọ̀na rẹ̀ ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli.
27 Ahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu na, ani ni Jerusalemu; ṣugbọn nwọn kò mu u wá sinu awọn isa-okú awọn ọba Israeli: Hesekiah ọmọ rẹ si jọba ni ipò rẹ̀.