2. Kro 8 YCE

Àwọn Àsẹyọrí Solomoni

1 O si ṣe lẹhin ogun ọdun ninu eyi ti Solomoni kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀.

2 Ni Solomoni kọ́ ilu wọnni ti Huramu fi fun Solomoni, o si mu ki awọn ọmọ Israeli ki o ma gbe ibẹ.

3 Solomoni si lọ si Hamati-Soba, o si bori rẹ̀.

4 O si kọ́ Tadmori li aginju, ati gbogbo ilu iṣura ti o kọ́ ni Hamati.

5 O kọ́ Bet-Horoni ti òke pẹlu, ati Bet-Horoni ti isalẹ, ilu odi, pẹlu ogiri, ilẹkun, ati ọpa-idabu;

6 Ati Baalati, ati gbogbo ilu iṣura ti Solomoni ni, ati gbogbo ilu kẹkẹ́, ati ilu ẹlẹṣin, ati gbogbo eyiti Solomoni fẹ lati kọ́ ni Jerusalemu, ati ni Lebanoni ati ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀.

7 Gbogbo awọn enia ti o kù ninu awọn ara Hitti, ati awọn Amori, ati awọn Peresi, ati awọn Hifi ati awọn Jebusi, ti kì iṣe ti inu ọmọ Israeli.

8 Ninu awọn ọmọ wọn, ti a ṣẹkù silẹ lẹhin wọn ni ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli kò run kuro, awọn ni Solomoni bu iṣẹ-ìrú fun titi o fi di oni yi.

9 Ṣugbọn ninu awọn ọmọ Israeli ni Solomoni kò fi ṣe ọmọ-ọdọ fun iṣẹ rẹ̀; nitori awọn li ọga-ogun ati olori awọn onikẹkẹ́ rẹ̀ ati awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀.

10 Awọn wọnyi li olori awọn alaṣẹ Solomoni ọba, adọtalerugba ti nṣakoso lori awọn enia.

11 Solomoni si mu ọmọbinrin Farao gòke lati ilu Dafidi wá si ile ti o kọ́ fun u; nitori ti o wipe, Ni temi, obinrin kan kì yio gbe inu ile Dafidi, ọba Israeli, nitori mimọ́ ni ibi ti apoti-ẹri Oluwa ti de.

12 Nigbana ni Solomoni ru ẹbọ ọrẹ-sisun si Oluwa lori pẹpẹ Oluwa, ti o ti tẹ niwaju iloro na.

13 Ani nipa ilana ojojumọ, lati ma rubọ gẹgẹ bi aṣẹ Mose, li ọjọjọ isimi, ati li oṣoṣu titun, ati ajọ mimọ́, lẹ̃mẹta li ọdun, ani li ajọ aiwukara, li ajọ ọsẹ-meje, ati li ajọ ipagọ.

14 O si yàn ipa awọn alufa, gẹgẹ bi ilana Dafidi baba rẹ̀, si ìsin wọn, ati awọn ọmọ Lefi si iṣẹ wọn, lati ma yìn, ati lati ma ṣe iranṣẹ niwaju awọn alufa, bi ilana ojojumọ: ati awọn adèna pẹlu ni ipa ti wọn li olukuluku ẹnu-ọ̀na: nitori bẹ̃ni Dafidi, enia Ọlọrun, ti pa a li aṣẹ.

15 Nwọn kò si yà kuro ninu ilana ọba nipa ti awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi niti olukuluku ọ̀ran, ati niti iṣura.

16 Gbogbo iṣẹ Solomoni li a ti pese silẹ bayi de ọjọ ifi-ipilẹ ile Oluwa le ilẹ titi o fi pari. A si pari ile Oluwa.

17 Nigbana ni Solomoni lọ si Esion-Geberi, ati si Eloti, ati si eti okun ni ilẹ Edomu.

18 Huramu si fi ọkọ̀ ranṣẹ si i, nipa ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn iranṣẹ ti o moye okun; nwọn si ba awọn iranṣẹ Solomoni lọ si Ofiri, lati ibẹ ni nwọn mu ãdọta-le-ni-irinwo talenti wura wá, nwọn si mu wọn tọ̀ Solomoni ọba wá.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36