1 HESEKIAH si ranṣẹ si gbogbo Israeli ati Juda, o si kọ iwe pẹlu si Efraimu ati Manasse, ki nwọn ki o wá sinu ile Oluwa ni Jerusalemu, lati pa ajọ irekọja mọ́ si Oluwa, Ọlọrun Israeli.
2 Nitoriti ọba ti gbìmọ ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo ijọ-enia ni Jerusalemu, lati pa ajọ irekọja mọ́ li oṣù keji.
3 Nitoriti nwọn kò le pa a mọ́ li akokò na, nitori awọn alufa kò ti iyà ara wọn si mimọ́ to; bẹ̃li awọn enia kò ti ikó ara wọn jọ si Jerusalemu.
4 Ọran na si tọ́ loju ọba ati loju gbogbo ijọ-enia.
5 Bẹ̃ni nwọn fi aṣẹ kan lelẹ, lati kede ká gbogbo Israeli, lati Beer-ṣeba ani titi de Dani, lati wá ipa ajọ irekọja mọ́ si Oluwa Ọlọrun Israeli ni Jerusalemu: nitori nwọn kò pa a mọ́ li ọjọ pupọ gẹgẹ bi a ti kọ ọ.
6 Bẹ̃li awọn onṣẹ ti nsare lọ pẹlu iwe lati ọwọ ọba ati awọn ijoye rẹ̀ si gbogbo Israeli ati Juda; ati gẹgẹ bi aṣẹ ọba, wipe, Ẹnyin ọmọ Israeli, ẹ tun yipada si Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, On o si yipada si awọn iyokù ninu nyin, ti o sala kuro lọwọ awọn ọba Assiria.
7 Ki ẹnyin ki o má si ṣe dabi awọn baba nyin, ati bi awọn arakunrin nyin, ti o dẹṣẹ si Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn, nitorina li o ṣe fi wọn fun idahoro, bi ẹnyin ti ri.
8 Njẹ ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọlọrùn lile, bi awọn baba nyin, ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Oluwa, ki ẹ si wọ̀ inu ibi-mimọ́ rẹ̀ lọ, ti on ti yà si mimọ́ titi lai: ki ẹ si sin Oluwa, Ọlọrun nyin, ki imuna ibinu rẹ̀ ki o le yipada kuro li ọdọ nyin.
9 Nitori bi ẹnyin ba tun yipada si Oluwa, awọn arakunrin nyin, ati awọn ọmọ nyin, yio ri ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni ìgbekun lọ, ki nwọn ki o le tun pada wá si ilẹ yi: nitori Oluwa Ọlọrun nyin, oniyọ́nu ati alãnu ni, kì yio si yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ nyin, bi ẹnyin ba pada sọdọ rẹ̀.
10 Bẹ̃ li awọn onṣẹ na kọja lati ilu de ilu, ni ilẹ Efraimu ati Manasse titi de Sebuluni: ṣugbọn nwọn fi wọn rẹrin ẹlẹya, nwọn si gàn wọn.
11 Sibẹ omiran ninu awọn enia Aṣeri ati Manasse ati Sebuluni rẹ̀ ara wọn silẹ, nwọn si wá si Jerusalemu.
12 Ni Judah pẹlu, ọwọ Ọlọrun wà lati fun wọn li ọkàn kan lati pa ofin ọba mọ́ ati ti awọn ijoye, nipa ọ̀rọ Oluwa.
13 Ọ̀pọlọpọ enia si pejọ ni Jerusalemu, lati pa ajọ akara alaiwu mọ́ li oṣu keji, ijọ enia nlanla.
14 Nwọn si dide, nwọn si kó gbogbo pẹpẹ ti o wà ni Jerusalemu lọ, ati gbogbo pẹpẹ turari ni nwọn kó lọ, nwọn si dà wọn si odò Kidroni.
15 Nigbana ni nwọn pa ẹran irekọja na li ọjọ kẹrinla oṣù keji: oju si tì awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, nwọn si yà ara wọn si mimọ́, nwọn si mu ẹbọ sisun wá sinu ile Oluwa.
16 Nwọn si duro ni ipò wọn, bi ètò wọn gẹgẹ bi ofin Mose, enia Ọlọrun: awọn alufa wọ́n ẹ̀jẹ na, ti nwọn gbà lọwọ awọn ọmọ Lefi.
17 Nitori ọ̀pọlọpọ li o wà ninu ijọ enia na ti kò yà ara wọn si mimọ́: nitorina ni awọn ọmọ Lefi ṣe ntọju ati pa ẹran irekọja fun olukuluku ẹniti o ṣe alaimọ́, lati yà a si mimọ́ si Oluwa.
18 Ọ̀pọlọpọ enia, ani ọ̀pọlọpọ ninu Efraimu ati Manasse, Issakari, ati Sebuluni kò sa wẹ̀ ara wọn mọ́ sibẹ nwọn jẹ irekọja na, kì iṣe gẹgẹ bi a ti kọ ọ. Ṣugbọn Hesekiah bẹ̀bẹ fun wọn, wipe, Oluwa, ẹni-rere, dariji olukuluku,
19 Ti o mura ọkàn rẹ̀ lati wá Ọlọrun, Oluwa Ọlọrun awọn baba rẹ̀, ṣugbọn ti kì iṣe nipa ìwẹnumọ́ mimọ́.
20 Oluwa si gbọ́ ti Hesekiah, o si mu awọn enia na lara dá.
21 Awọn ọmọ Israeli ti a ri ni Jerusalemu fi ayọ̀ nla pa ajọ àkara alaiwu mọ́ li ọjọ meje: awọn ọmọ Lefi, ati awọn alufa yìn Oluwa lojojumọ, nwọn nfi ohun-elo olohùn goro kọrin si Oluwa.
22 Hesekiah sọ̀rọ itunu fun gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o loye ni ìmọ rere Oluwa: ijọ meje ni nwọn fi jẹ àse na, nwọn nru ẹbọ alafia, nwọn si nfi ohùn rara dupẹ fun Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn.
23 Gbogbo ijọ na si gbìmọ lati pa ọjọ meje miran mọ́: nwọn si fi ayọ̀ pa ọjọ meje miran mọ́.
24 Nitori Hesekiah, ọba Juda, ta ijọ enia na li ọrẹ, ẹgbẹrun akọ-malu, ati ẹ̃dẹgbãrun àgutan: ọ̀pọlọpọ ninu awọn alufa si yà ara wọn si mimọ́.
25 Gbogbo ijọ-enia Juda pẹlu awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo ijọ-enia ti o ti inu Israeli jade wá, ati awọn àlejo ti o ti ilẹ Israeli jade wá, ati awọn ti ngbe Juda yọ̀.
26 Bẹ̃li ayọ̀ nla si wà ni Jerusalemu: nitori lati ọjọ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, iru eyi kò sí ni Jerusalemu.
27 Nigbana li awọn alufa, awọn ọmọ Lefi dide, nwọn si sure fun awọn enia na: a si gbọ́ ohùn wọn, adura wọn si gòke lọ si ibugbe mimọ́ rẹ̀, ani si ọrun.