1 BAYI ni gbogbo iṣẹ ti Solomoni ṣe fun ile Oluwa pari: Solomoni si mu gbogbo nkan ti Dafidi baba rẹ̀ ti yà si mimọ́ wá sinu rẹ̀; ati fadakà, ati wura, ati gbogbo ohun-elo, li o fi sinu iṣura ile Ọlọrun.
2 Nigbana ni Solomoni pe awọn àgbagba Israeli jọ, ati gbogbo olori awọn baba awọn ọmọ Israeli si Jerusalemu, lati mu apoti-ẹri majẹmu Oluwa gòke lati ilu Dafidi wá, ti iṣe Sioni.
3 Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si pejọ sọdọ ọba li ajọ, eyi ni oṣù keji.
4 Gbogbo awọn àgbagba Israeli si wá; awọn ọmọ Lefi si gbé apoti-ẹri na.
5 Nwọn si gbé apoti-ẹri na gòke, ati agọ ajọ, ati gbogbo ohun-elo mimọ́ ti o wà ninu agọ, wọnyi ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi mu gòke wá.
6 Solomoni ọba, ati gbogbo ijọ enia Israeli ti o pejọ si ọdọ rẹ̀, wà niwaju apoti-ẹrí na, nwọn si fi agutan ati malu rubọ, ti a kò le kà, bẹ̃ni a kò le mọ̀ iye wọn fun ọ̀pọlọpọ.
7 Awọn alufa si gbé apoti-ẹri ti majẹmu Oluwa wá si ipò rẹ̀, si ibi-idahùn ile na, sinu ibi-mimọ́-jùlọ, labẹ iyẹ awọn kerubu:
8 Bẹ̃ni awọn kerubu nà iyẹ wọn bò ibi apoti-ẹri na, awọn kerubu si bò apoti-ẹri na, ati awọn ọpa rẹ̀ lati òke wá.
9 Ọpa rẹ̀ wọnni si gùn tobẹ̃, ti a fi ri ori awọn ọpa na lati ibi apoti-ẹri na niwaju ibi mimọ́-jùlọ na, ṣugbọn a kò ri wọn li ode. Nibẹ li o si wà titi di oni yi.
10 Kò si ohun kan ninu apoti-ẹri na bikòṣe walã meji ti Mose fi sinu rẹ̀ ni Horebu, nigbati Oluwa fi ba awọn ọmọ Israeli dá majẹmu, nigbati nwọn ti Egipti jade wá.
11 O si ṣe, nigbati awọn alufa ti ibi mimọ́ jade wá; (nitori gbogbo awọn alufa ti a ri li a yà si mimọ́, nwọn kò si kiyesi ipa wọn nigbana:
12 Awon ọmọ Lefi pẹlu ti iṣe akọrin, gbogbo wọn ti Asafu, ti Hemani, ti Jedutuni, pẹlu awọn ọmọ wọn ati awọn arakunrin wọn, nwọn wọ ọ̀gbọ funfun, nwọn ni kimbali, ati ohun-elo orin, ati duru, nwọn si duro ni igun ila-õrun pẹpẹ na, ati pẹlu wọn, ìwọn ọgọfa alufa ti nwọn nfún ipè:)
13 O si ṣe bi ẹnipe ẹnikan, nigbati a gbọ́ ohùn awọn afunpè ati awọn akọrin, bi ohùn kan lati ma yìn, ati lati ma dupẹ fun Oluwa; nigbati nwọn si gbé ohùn wọn soke pẹlu ipè ati kimbali, ati ohun-elo orin, lati ma yìn Oluwa pe, O ṣeun; ãnu rẹ̀ si duro lailai: nigbana ni ile na kún fun awọsanmọ, ani ile Oluwa;
14 Tobẹ̃ ti awọn alufa kò le duro lati ṣiṣẹ ìsin nitori awọsanmọ na: nitori ogo Oluwa kún ile Ọlọrun.