1 NIGBANA ni Solomoni wipe, Oluwa ti wipe, on o ma gbe inu òkunkun biribiri.
2 Ṣugbọn emi ti kọ́ ile ibugbe kan fun ọ, ati ibi kan fun ọ lati ma gbe titi lai.
3 Ọba si yi oju Rẹ̀, o si fi ibukún fun gbogbo ijọ awọn enia Israeli; gbogbo ijọ awọn enia Israeli si dide duro.
4 O si wipe, Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ọwọ rẹ̀ mu eyi ti o ti fi ẹnu rẹ̀ sọ fun Dafidi baba mi ṣẹ, wipe,
5 Lati ọjọ ti emi ti mu awọn enia mi jade kuro ni ilẹ Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli lati kọ́ ile, ki orukọ mi ki o wà nibẹ; bẹ̃ni emi kò yàn ọkunrin kan lati ṣe olori Israeli awọn enia mi:
6 Ṣugbọn emi ti yàn Jerusalemu, ki orukọ mi ki o le wà nibẹ; mo si ti yàn Dafidi lati wà lori Israeli, enia mi.
7 O si ti wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli:
8 Oluwa si sọ fun Dafidi baba mi pe, nitoriti o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile fun orukọ mi, iwọ ṣeun li eyiti o wà li ọkàn rẹ.
9 Sibẹ iwọ kò gbọdọ kọ́ ile na; ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio jade ti inu rẹ wá ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi.
10 Oluwa si ti mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ; emi si dide ni ipò Dafidi baba mi, a si gbé mi ka itẹ́ Israeli bi Oluwa ti ṣe ileri, emi si ti kọ́ ile na fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli.
11 Ati ninu rẹ̀ ni mo fi apoti-ẹri na si, ninu eyiti majẹmu Oluwa wà, ti o ba awọn ọmọ Israeli dá.
12 On si duro niwaju pẹpẹ Oluwa, niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ ọwọ rẹ̀ mejeji.
13 Nitori Solomoni ṣe aga idẹ kan, igbọnwọ marun ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni gbigboro, ati igbọnwọ mẹta ni giga, o si gbé e si ãrin agbala na; lori rẹ̀ li o duro, o si kunlẹ lori ẽkun rẹ̀ niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji soke ọrun,
14 O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ li ọrun tabi li aiye: ti npa majẹmu mọ́, ati ãnu fun awọn iranṣẹ rẹ, ti nfi tọkàntọkan wọn rìn niwaju rẹ.
15 Iwọ ti o ti ba iranṣẹ rẹ Dafidi baba mi, pa eyi ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́; ti iwọ si ti fi ẹnu rẹ sọ, ti iwọ si ti fi ọwọ rẹ mu u ṣẹ, bi o ti ri loni yi.
16 Njẹ nisisiyi, Oluwa, Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa eyi ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́, wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ́ Israeli: kiki bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati ma rìn ninu ofin mi, bi iwọ ti rìn niwaju mi.
17 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun Israeli, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o ṣẹ, ti iwọ ti sọ fun Dafidi, iranṣẹ rẹ,
18 Ni otitọ ni Ọlọrun yio ha ma ba enia gbe li aiye? Kiyesi i, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọsi ile yi ti emi kọ́!
19 Sibẹ, iwọ ṣe afiyesi adura iranṣẹ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati adura ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ:
20 Ki oju rẹ ki o le ṣí si ile yi lọsan ati loru, ani si ibi ti iwọ ti wipe, iwọ o fi orukọ rẹ sibẹ; lati tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ ngbà si ibi yi.
21 Nitorina gbọ́ ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ, ati ti Israeli enia rẹ ti nwọn o ma gbà si ibi yi: iwọ gbọ́ lati ibugbe rẹ wá, ani lati ọrun wá, nigbati iwọ ba gbọ́, ki o si dariji.
22 Bi ọkunrin kan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, ti ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi;
23 Nigbana ni ki o gbọ́ lati ọrun wá, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni sisan a fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ pada sori on tikararẹ̀; ati ni didare fun olododo, lati fifun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀.
24 Bi a ba si fọ́ awọn enia rẹ Israeli bajẹ niwaju ọta, nitori ti nwọn ti dẹṣẹ si ọ; ti nwọn ba si pada ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn si gbadura, ti nwọn si bẹ̀bẹ niwaju rẹ ni ile yi;
25 Nigbana ni ki o gbọ́ lati ọrun wá, ki o si dari ẹ̀ṣẹ Israeli enia rẹ jì, ki o si mu wọn pada wá si ilẹ ti iwọ ti fi fun wọn ati fun awọn baba wọn.
26 Nigbati a ba se ọrun mọ́ ti kò si sí òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ; ṣugbọn bi nwọn ba gbadura si ibi yi, ti nwọn ba jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nitoriti iwọ pọn wọn loju.
27 Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ ji, ati ti Israeli enia rẹ, nigbati iwọ ba ti kọ́ wọn li ọ̀na rere na, ninu eyiti nwọn o ma rìn: ki o si rọ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun awọn enia rẹ ni ini.
28 Bi ìyan ba mu ni ilẹ, bi àjakalẹ-arun ba wà, bi irẹ̀danu ba wà, tabi eṣú ti njẹrun, bi awọn ọta wọn ba yọ wọn li ẹnu ni ilẹ ilu wọn; oniruru ipọnju tabi oniruru àrun.
29 Adura ki adura, tabi ẹ̀bẹ ki ẹ̀bẹ ti a ba ti ọdọ ẹnikẹni gbà, tabi ọdọ gbogbo Israeli enia rẹ, nigbati olukuluku ba mọ̀ ipọnju rẹ̀, ati ibanujẹ rẹ̀, ti o ba si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji siha ile yi:
30 Ki iwọ ki o gbọ́ lati ọrun, ibugbe rẹ wá, ki o si dariji, ki o si san a fun olukuluku gẹgẹ bi gbogbo ọ̀na rẹ̀, bi iwọ ti mọ̀ ọkàn rẹ̀; (nitori iwọ nikanṣoṣo li o mọ̀ ọkàn awọn ọmọ enia:)
31 Ki nwọn ki o le bẹ̀ru rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ, li ọjọ gbogbo ti nwọn o wà ni ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa.
32 Pẹlupẹlu niti alejo, ti kì iṣe inu Israeli, enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ òkere jade wá nitori orukọ nla rẹ, ati ọwọ agbara rẹ ati ninà apa rẹ; bi nwọn ba wá ti nwọn ba si gbadura siha ile yi:
33 Ki iwọ ki o gbọ́ lati ọrun, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejo na kepe ọ si; ki gbogbo enia aiye ki o le mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o si le ma bẹ̀ru rẹ̀, bi Israeli enia rẹ, ki nwọn ki o le mọ̀ pe orukọ rẹ li a npè mọ ile yi ti emi kọ́.
34 Bi awọn enia rẹ ba jade lọ si ogun si ọta wọn li ọ̀na ti iwọ o rán wọn, ti nwọn ba si gbadura si ọ, siha ilu yi, ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi ti kọ́ fun orukọ rẹ:
35 Ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn lati ọrun wa, ki o si mu ọ̀ran wọn duro.
36 Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ (nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀,) bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le awọn ọta lọwọ, ti nwọn ba si kó wọn ni igbekun lọ si ilẹ ti o jìna rére, tabi ti o wà nitosi.
37 Ṣugbọn, bi nwọn ba rò inu ara wọn wò, ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbekun lọ, ti nwọn ba si yipada, ti nwọn ba si gbadura si ọ li oko ẹrú wọn, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣìṣe, awa si ti ṣe buburu;
38 Bi nwọn ba si fi gbogbo aiya ati gbogbo ọkàn wọn yipada si ọ li oko ẹrú wọn, si ibi ti a gbe kó wọn lọ, ti nwọn ba si gbadura siha ilẹ wọn, ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn, ati siha ilu na ti iwọ ti yàn, ati siha ile na ti emi ti kọ́ fun orukọ rẹ:
39 Ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn lati ọrun wá, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si mu ọ̀ran wọn duro, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn enia rẹ jì ti nwọn ti da si ọ.
40 Nisisiyi Ọlọrun mi, jẹ ki oju rẹ ki o ṣí, ki o si tẹtisilẹ si adura si ihinyi.
41 Njẹ nisisiyi, dide, Oluwa Ọlọrun si ibi isimi rẹ, iwọ ati apoti agbara rẹ; jẹ ki a fi igbala wọ̀ awọn alufa rẹ, Oluwa Ọlọrun, ki o si jẹ ki awọn enia ayanfẹ rẹ ki o ma yọ̀ ninu ire.
42 Oluwa Ọlọrun, máṣe yi oju ẹni ororo rẹ pada: ranti ãnu fun Dafidi, iranṣẹ rẹ.