1 REHOBOAMU si lọ si Ṣekemu: nitori gbogbo Israeli wá si Ṣekemu lati fi i jẹ ọba.
2 O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọmọ Nebati gbọ́, on si wà ni Egipti nibiti o ti salọ kuro niwaju Solomoni ọba, ni Jeroboamu pada ti Egipti wá.
3 Nwọn si ranṣẹ pè e. Bẹ̃ni Jeroboamu ati gbogbo Israeli wá, nwọn si ba Rehoboamu sọ̀rọ, wipe,
4 Baba rẹ mu ki àjaga wa ki o wuwo: njẹ nisisiyi iwọ ṣẹkù kuro ninu ìsin baba rẹ ti o nira, ati àjaga wuwo rẹ̀ ti o fi bọ̀ wa lọrùn, awa o si ma sìn ọ.