11 Njẹ nisisiyi baba mi ti fi àjaga wuwo bọ̀ nyin lọrùn, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin.
12 Jeroboamu ati gbogbo awọn enia si tọ̀ Rehoboamu wá ni ijọ kẹta gẹgẹ bi ọba ti dá, wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta.
13 Nigbana ni ọba da wọn li ohùn akọ; Rehoboamu ọba si kọ̀ imọran awọn àgbagba silẹ.
14 O si da wọn li ohùn gẹgẹ bi imọran awọn ipẹrẹ, wipe, Baba mi mu àjaga nyin ki o wuwo, ṣugbọn emi o fi kún u; baba mi ti fi paṣan nà nyin, ṣugbọn emi o fi akẽke nà nyin.
15 Bẹ̃ni ọba kò si fetisi ti awọn enia na: nitori ṣiṣẹ ọ̀ran na lati ọwọ Ọlọrun wá ni, ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, ti o sọ nipasẹ Ahijah, ara Ṣilo fun Jeroboamu, ọmọ Nebati.
16 Nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kọ̀ lati fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba lohùn, wipe, Ipin kili a ni ninu Dafidi? awa kò si ni ini kan ninu ọmọ Jesse: Israeli, olukuluku sinu agọ rẹ̀: nisisiyi Dafidi, mã bojuto ile rẹ. Bẹ̃ni gbogbo Israeli lọ sinu agọ wọn,
17 Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli ti ngbe ilu Juda wọnni, Rehoboamu jọba lori wọn.