6 Rehoboamu ọba si ba awọn àgbagba ti o ti nduro niwaju Solomoni baba rẹ̀; nigbati o wà lãye dá imọran, wipe, imọran kili ẹnyin dá lati da awọn enia yi lohùn?
7 Nwọn si ba a sọ̀rọ pe, bi iwọ ba ṣe ire fun enia yi, ti iwọ ba ṣe ohun ti o wù wọn, ti o ba si sọ̀rọ rere fun wọn, nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ nigbagbogbo.
8 Ṣugbọn o kọ̀ imọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti o dàgba pẹlu rẹ̀ damọran, ti o duro niwaju rẹ̀.
9 On si wi fun wọn pe, Imọran kili ẹnyin dá, ki awa ki o le da awọn enia yi lohùn, ti o ba mi sọ̀rọ, wipe, Ṣe ki àjaga ti baba rẹ fi bọ̀ wa lọrùn ki o fuyẹ diẹ?
10 Awọn ipẹrẹ ti a tọ́ pẹlu rẹ̀ si sọ fun u wipe, Bayi ni iwọ o da awọn enia na li ohùn ti o sọ fun ọ, wipe, Baba rẹ mu àjaga wa di wuwo, ṣugbọn iwọ ṣe e ki o fẹrẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o wi fun wọn, Ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ.
11 Njẹ nisisiyi baba mi ti fi àjaga wuwo bọ̀ nyin lọrùn, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin.
12 Jeroboamu ati gbogbo awọn enia si tọ̀ Rehoboamu wá ni ijọ kẹta gẹgẹ bi ọba ti dá, wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta.