12 Ati ni olukuluku ilu li o fi asà ati ọ̀kọ si, o si mu wọn lagbara gidigidi, o si ni Juda ati Benjamini labẹ rẹ̀.
13 Ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ti o wà ni gbogbo Israeli, tọ̀ ọ lọ lati gbogbo ibugbe wọn wá.
14 Nitori ti awọn ọmọ Lefi fi ìgberiko wọn silẹ, ati ini wọn, nwọn si lọ si Juda ati Jerusalemu: nitori Jeroboamu ati awọn ọmọ rẹ̀ ti le wọn kuro lati ma ṣiṣẹ alufa fun Oluwa.
15 O si yàn awọn alufa fun ibi-giga wọnni, ati fun awọn ere-obukọ ati fun ẹ̀gbọrọ-malu ti o ti ṣe.
16 Lẹhin wọn iru awọn ti o fi ọkàn wọn si ati wá Oluwa Ọlọrun Israeli lati inu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli wá, si wá si Jerusalemu, lati ṣe irubọ si Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn.
17 Bẹ̃ni nwọn si mu ijọba Juda lagbara, nwọn mu ki Rehoboamu, ọmọ Solomoni ki o lagbara li ọdun mẹta: nitori li ọdun mẹta ni nwọn rìn li ọ̀na Dafidi ati Solomoni.
18 Rehoboamu si mu Mahalati, ọmọbinrin Jerimoti, ọmọ Dafidi, li aya, ati Abihaili, ọmọbinrin Eliabi, ọmọ Jesse: