16 Lẹhin wọn iru awọn ti o fi ọkàn wọn si ati wá Oluwa Ọlọrun Israeli lati inu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli wá, si wá si Jerusalemu, lati ṣe irubọ si Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn.
17 Bẹ̃ni nwọn si mu ijọba Juda lagbara, nwọn mu ki Rehoboamu, ọmọ Solomoni ki o lagbara li ọdun mẹta: nitori li ọdun mẹta ni nwọn rìn li ọ̀na Dafidi ati Solomoni.
18 Rehoboamu si mu Mahalati, ọmọbinrin Jerimoti, ọmọ Dafidi, li aya, ati Abihaili, ọmọbinrin Eliabi, ọmọ Jesse:
19 Ẹniti o bi ọmọkunrin wọnyi fun u; Jeuṣi, ati Ṣamariah, ati Sahamu.
20 Ati lẹhin rẹ̀, o mu Maaka, ọmọbinrin Absalomu ti o bi Abijah fun u, ati Attai, ati Sisa, ati Ṣelomiti.
21 Rehoboamu si fẹran Maaka ọmọbinrin Absalomu, jù gbogbo awọn aya rẹ̀ ati àle rẹ̀ lọ: (nitoriti o ni aya mejidilogun, ati ọgọta àle: o si bi ọmọkunrin mejidilọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin).
22 Rehoboamu si ṣe Abijah, ọmọ Maaka, li olori lati ṣe olori ninu awọn arakunrin rẹ̀: nitori ti o rò lati fi i jọba.