17 Bẹ̃ni nwọn si mu ijọba Juda lagbara, nwọn mu ki Rehoboamu, ọmọ Solomoni ki o lagbara li ọdun mẹta: nitori li ọdun mẹta ni nwọn rìn li ọ̀na Dafidi ati Solomoni.
18 Rehoboamu si mu Mahalati, ọmọbinrin Jerimoti, ọmọ Dafidi, li aya, ati Abihaili, ọmọbinrin Eliabi, ọmọ Jesse:
19 Ẹniti o bi ọmọkunrin wọnyi fun u; Jeuṣi, ati Ṣamariah, ati Sahamu.
20 Ati lẹhin rẹ̀, o mu Maaka, ọmọbinrin Absalomu ti o bi Abijah fun u, ati Attai, ati Sisa, ati Ṣelomiti.
21 Rehoboamu si fẹran Maaka ọmọbinrin Absalomu, jù gbogbo awọn aya rẹ̀ ati àle rẹ̀ lọ: (nitoriti o ni aya mejidilogun, ati ọgọta àle: o si bi ọmọkunrin mejidilọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin).
22 Rehoboamu si ṣe Abijah, ọmọ Maaka, li olori lati ṣe olori ninu awọn arakunrin rẹ̀: nitori ti o rò lati fi i jọba.
23 On si huwà ọlọgbọ́n, o si tú ninu gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ka si gbogbo ilẹ Juda ati Benjamini, si olukuluku ilu olodi: o si fun wọn li onjẹ li ọ̀pọlọpọ. O si fẹran ọ̀pọlọpọ obinrin.