6 O kọ́ Betlehemu pẹlu, ati Etamu, ati Tekoa,
7 Ati Bet-Suri, ati Soko, ati Adullamu,
8 Ati Gati, ati Mareṣa, ati Sifu,
9 Ati Adoraimu, ati Lakiṣi, ati Aseki,
10 Ati Sora, ati Aijaloni, ati Hebroni, ti o wà ni Juda ati ni Benjamini, awọn ilu olodi.
11 O si mu awọn ilu olodi lagbara, o si fi awọn balogun sinu wọn ati akojọ onjẹ, ati ororo ati ọti-waini.
12 Ati ni olukuluku ilu li o fi asà ati ọ̀kọ si, o si mu wọn lagbara gidigidi, o si ni Juda ati Benjamini labẹ rẹ̀.