13 Ṣugbọn Jeroboamu mu ki ogun-ẹ̀hin ki o bù wọn li ẹhin: bẹ̃ni nwọn mbẹ niwaju Juda, ati ogun-ẹhin na si mbẹ lẹhin wọn.
14 Nigbati Juda si bojuwo ẹhin, si kiyesi i, ogun mbẹ niwaju ati lẹhin: nwọn si ke pè Oluwa, awọn alufa si fún ipè.
15 Olukuluku, ọkunrin Juda si hó: o si ṣe, bi awọn ọkunrin Juda si ti hó, ni Ọlọrun kọlu Jeroboamu ati gbogbo Israeli niwaju Abijah ati Juda.
16 Awọn ọmọ Israeli si sa niwaju Juda: Ọlọrun si fi wọn le wọn lọwọ.
17 Abijah ati awọn enia rẹ̀ si pa ninu wọn li ọ̀pọlọpọ: bẹ̃ni ọkẹ mẹdọgbọn ọkunrin ti a yàn ṣubu ni pipa ninu Israeli.
18 Bayi li a rẹ̀ awọn ọmọ Israeli silẹ li akoko na, awọn ọmọ Juda si bori nitori ti nwọn gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn.
19 Abijah si lepa Jeroboamu, o si gbà ilu lọwọ rẹ̀, Beteli pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Jeṣana pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Efraimu pẹlu awọn ilu rẹ̀.