1 ẸMI Ọlọrun si wá si ara Asariah, ọmọ Odedi:
2 O si jade lọ ipade Asa, o si wi fun u pe, Ẹ gbọ́ temi, Asa, ati gbogbo Juda ati Benjamini! Oluwa pẹlu nyin, nitori ti ẹnyin ti wà pẹlu rẹ̀; bi ẹnyin ba si ṣafẹri rẹ̀, ẹnyin o ri i; ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ̀ ọ, on o si kọ̀ nyin.
3 Njẹ ọjọ pupọ ni Israeli ti wà laisìn Ọlọrun otitọ, ati laini alufa ti nkọni, ati laini ofin.
4 Ṣugbọn nwọn yipada si Oluwa. Ọlọrun Israeli, ninu wahala wọn, nwọn si ṣe awari rẹ̀, nwọn si ri i.