15 Gbogbo Juda si yọ̀ si ibura na: nitoriti nwọn fi tinu-tinu wọn bura, nwọn si fi gbogbo ifẹ inu wọn wá a; nwọn si ri i: Oluwa si fun wọn ni isimi yikakiri.
16 Pẹlupẹlu Maaka, iya Asa, li ọba mu u kuro lati má ṣe ayaba, nitoriti o yá ere fun oriṣa rẹ̀: Asa si ké ere rẹ̀ lulẹ, o si tẹ̀ ẹ mọlẹ, o si sun u nibi odò Kidroni.
17 Ṣugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro ni Israeli: kiki ọkàn Asa wà ni pipé li ọjọ rẹ̀ gbogbo.
18 O si mu ohun mimọ́ wọnni ti baba rẹ̀, ati ohun mimọ́ wọnni ti on tikararẹ̀ wá sinu ile Ọlọrun, fadakà, wura, ati ohun-elo wọnni.
19 Ogun kò si mọ titi di ọdun karundilogoji ọba Asa.