1 JEHOṢAFATI, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀, o si mu ara rẹ̀ le si Israeli.
2 O si fi ogun sinu gbogbo ilu olodi Juda, o si fi ẹgbẹ-ogun si ilẹ Juda ati sinu ilu Efraimu wọnni, ti Asa baba rẹ̀ ti gbà.
3 Oluwa si wà pẹlu Jehoṣafati, nitoriti o rìn ninu ọ̀na iṣaju Dafidi, baba rẹ̀, kò si wá Baalimu:
4 Ṣugbọn o wá Ọlọrun baba rẹ̀, o si rìn ninu ofin rẹ̀, ki iṣe bi iṣe Israeli.
5 Nitorina ni Oluwa fi idi ijọba na mulẹ li ọwọ rẹ̀; gbogbo Juda si ta Jehoṣafati li ọrẹ, on si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ.
6 Ọkàn rẹ̀ si gbé soke li ọ̀na Oluwa: pẹlupẹlu o si mu ibi giga wọnni ati ere-oriṣa kuro ni Juda.
7 Ati li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o ranṣẹ si awọn ijoye rẹ̀, ani si Benhaili ati si Obadiah ati Sekariah, ati si Netaneeli, ati si Mikaiah, lati ma kọ́ni ninu ilu Juda wọnni.