7 Ati li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o ranṣẹ si awọn ijoye rẹ̀, ani si Benhaili ati si Obadiah ati Sekariah, ati si Netaneeli, ati si Mikaiah, lati ma kọ́ni ninu ilu Juda wọnni.
8 Ati pẹlu wọn, o rán awọn ọmọ Lefi, ani Ṣemaiah, ati Netaniah, ati Sebadiah, ati Asaheli, ati Ṣemiramotu, ati Jehonatani, ati Adonijah, ati Tobijah, ati Tob-Adonijah, awọn ọmọ Lefi; ati pẹlu wọn Eliṣama, ati Jehoramu, awọn alufa.
9 Nwọn si kọ́ni ni Juda, nwọn si ni ofin Oluwa pẹlu wọn, nwọn si lọ kakiri ja gbogbo ilu Juda, nwọn si kọ́ awọn enia.
10 Ẹ̀ru Oluwa si ba gbogbo ijọba ilẹ na, ti o wà yikakiri Juda, tobẹ̃ ti nwọn kò ba Jehoṣafati jagun kan.
11 Ati ninu awọn ara Filistia mu ọrẹ fun Jehoṣafati wá, ati fadakà owo ọba: awọn ara Arabia si mu ọwọ́-ẹran fun u wá, ẹgbãrin àgbo o di ọ̃dunrun, ati ẹgbãrin obukọ di ọ̃dunrun.
12 Jehoṣafati si npọ̀ si i gidigidi: o si kọ́ ile olodi, ati ilu iṣura ni Juda.
13 O si ni iṣura pupọ ni ilu Juda; ati awọn jagunjagun, awọn alagbara akọni ọkunrin ti o wà ni Jerusalemu.