13 Mikaiah si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ani, eyiti Ọlọrun mi ba wi li emi o sọ.
14 Nigbati o si tọ̀ ọba wá, ọba sọ fun u pe, Mikaiah, ki awa ki o lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? O si wipe, Ẹ lọ, ẹnyin o si ṣe rere, a o si fi wọn le nyin lọwọ.
15 Ọba si wi fun u pe, Igba melo li emi o fi ọ bú ki iwọ ki o máṣe sọ ohun kan fun mi bikòṣe ọ̀rọ otitọ li orukọ Oluwa?
16 On si wipe, Emi ri gbogbo Israeli fọnka kiri lori awọn òke, bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa: jẹ ki nwọn ki o pada, olukuluku si ile rẹ̀ li alafia.
17 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi kò ti wi fun ọ pe: on kì isọtẹlẹ rere si mi, bikòṣe ibi?
18 Mikaiah si wipe, Nitorina, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun ọrun duro lapa ọtún ati lapa òsi rẹ̀.
19 Oluwa si wipe, Tani yio tàn Ahabu, ọba Israeli, ki o le gòke lọ ki o si le ṣubu ni Ramoti-Gileadi? Ekini si sọ bayi, ekeji si sọ miran.