6 Ṣugbọn Jehoṣafati wipe, kò si woli Oluwa nihin pẹlu, ti awa ìba bère lọwọ rẹ̀?
7 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan mbẹ sibẹ lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀: nitoriti kò jẹ sọ asọtẹlẹ rere si mi lai, bikòṣe ibi nigbagbogbo: eyini ni Mikaiah, ọmọ Imla. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba ki o má sọ bẹ̃.
8 Ọba Israeli si pè ìwẹfa kan, o si wipe, Mu ki Mikaiah ọmọ Imla, ki o yara wá.
9 Ati ọba Israeli, ati Jehoṣafati, ọba Juda joko, olukuluku lori itẹ rẹ̀, nwọn si wọ aṣọ igunwa wọn, nwọn si joko ni ita ẹnubọde Samaria; gbogbo awọn woli si nsọ asọtẹlẹ niwaju wọn.
10 Sedekiah ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn awọn ara Siria titi iwọ o fi run wọn.
11 Gbogbo awọn woli si nsọtẹlẹ bẹ̃ wipe, Gòke lọ si Ramoti-Gileadi, iwọ o ṣe rere; Oluwa yio si fi i le ọba lọwọ.
12 Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah si wi fun u pe, Kiye si i, awọn woli fi ẹnu kan sọ rere fun ọba: Njẹ emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọkan ninu ti wọn, ki o si sọ rere.