2. Kro 2:2-8 YCE

2 Solomoni si yàn ẹgbã marundilogoji ọkunrin lati ru ẹrù, ati ọkẹ mẹrin lati ké igi li ori òke, ati egbejidilogun lati bojuto wọn.

3 Solomoni si ranṣẹ si Huramu, ọba Tire, wipe, Gẹgẹ bi iwọ ti ba Dafidi, baba mi lò, ti iwọ fi igi kedari ṣọwọ si i lati kọ́ ile kan fun u lati ma gbe inu rẹ̀, bẹni ki o ba mi lò.

4 Kiyesi i, emi nkọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun mi, lati yà a si mimọ́ fun u, ati lati sun turari niwaju rẹ̀, ati fun àkara-ifihan igbakugba, ati fun ẹbọsisun li ọwurọ ati li alẹ, li ọjọjọ isimi ati li oṣoṣù titun, ati li apejọ Oluwa Ọlọrun wa; eyi ni aṣẹ fun Israeli titi lai.

5 Ile ti emi nkọ́ yio si tobi; nitori titobi ni Ọlọrun wa jù gbogbo awọn ọlọrun lọ.

6 Ṣugbọn tani to lati kọ́ ile fun u, nitori ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà a? tali emi ti emi iba kọ́le fun u, bikòṣe kiki ati sun ẹbọ niwaju rẹ̀?

7 Njẹ nisisiyi rán ọkunrin kan si mi ti o gbọ́n lati ṣiṣẹ ni wura, fadakà, ati ni idẹ, ati ni irin, ati ni èse aluko, ati òdodó ati alaró, ti o si le gbọ́ngbọn ati gbẹgi pẹlu awọn ọkunrin ọlọgbọ́n ti o wà lọdọ mi ni Juda ati Jerusalemu, awọn ẹniti Dafidi baba mi ti pese silẹ.

8 Fi ìti-igi kedari, ati firi, ati algumu ranṣẹ si mi pẹlu, lati Lebanoni wá: emi sa mọ̀ pe awọn iranṣẹ rẹ le gbọ́ngbọn ati ké igi ni Lebanoni; si kiyesi i, awọn ọmọ-ọdọ mi yio wà pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ: