12 Iwe kan si ti ọdọ Elijah, woli, wá si ọdọ rẹ̀ wipe: Bayi li Oluwa, Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi, nitoriti iwọ kò rìn li ọ̀na Jehoṣafati, baba rẹ, tabi li ọ̀na Asa, ọba Juda;
13 Ṣugbọn ti iwọ rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, iwọ si ti mu Juda ati awọn olugbe Jerusalemu tọ ọ̀na panṣaga, gẹgẹ bi panṣaga ile Ahabu, ati ti iwọ si pa awọn arakunrin ile baba rẹ ti o jẹ ẹni-rere jù iwọ lọ:
14 Kiyesi i, Oluwa yio fi àjakalẹ-arun nla kọlù awọn enia rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn obinrin rẹ, ati gbogbo ọrọ̀ rẹ:
15 Iwọ o ṣe aisan pupọ, àrun nla ninu ifun rẹ, titi ifun rẹ yio fi tu jade nitori àrun ọjọ pupọ.
16 Pẹlupẹlu, Oluwa ru ẹmi awọn ara Filistia, ati ti awọn ara Arabia, ti o sunmọ awọn ara Etiopia, soke si Jehoramu.
17 Nwọn si gòke wá si Juda, nwọn si ya wọle, nwọn si kó gbogbo ọrọ̀ ti a ri ni ile ọba ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, ati awọn obinrin rẹ̀, ni igbekun lọ; tobẹ̃ ti a kò ṣẹ́ku ọkunrin kan silẹ fun u, bikòṣe Jehoahasi, abikẹhin ninu awọn ọmọ rẹ̀.
18 Lẹhin gbogbo eyi Oluwa fi àrun, ti a kò le wòsan, kọlù u ni ifun.