3 Gbogbo ijọ enia si ba ọba dá majẹmu ni ile Ọlọrun. O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, ọmọ ọba ni yio jọba, gẹgẹ bi Oluwa ti wi niti awọn ọmọ Dafidi.
4 Eyi li ohun ti ẹnyin o ṣe; Idamẹta nyin yio wọle li ọjọ isimi, ninu awọn alufa ati ninu awọn ọmọ Lefi, ti yio ṣe adena iloro;
5 Idamẹta yio wà ni ile ọba: idamẹta yio si wà ni ẹnu-ọ̀na ti a npè ni ile Ipilẹ: ati gbogbo enia yio wà li àgbala ile Oluwa.
6 Ṣugbọn ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o wọ̀ ile Oluwa wá, bikoṣe awọn alufa, ati awọn ti nṣe iranṣẹ fun awọn ọmọ Lefi: nwọn o wọle, nitori mimọ́ ni nwọn: gbogbo awọn enia yio si ṣọ́ ẹṣọ́ Oluwa.
7 Awọn ọmọ Lefi yio yi ọba ka kakiri, olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀: ẹnikẹni ti o ba wá si iha ile na, a o si pa a: ṣugbọn ki ẹnyin ki o wà pẹlu ọba, nigbati o ba nwọ̀ ile, ati nigbati o ba njade.
8 Bẹ̃li awọn ọmọ Lefi ati gbogbo Juda ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada, alufa ti pa á ni aṣẹ, olukuluku si mu awọn enia rẹ̀ ti o nwọle li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti o njade li ọjọ isimi nitori Jehoiada alufa, kò jọwọ awọn ẹgbẹ meji alufa lọwọ lọ.
9 Jehoiada alufa, si fi ọ̀kọ ati asà, ati apata wọnni ti iti ṣe ti Dafidi ọba, ti o ti wà ni ile Ọlọrun, fun awọn balogun ọrọrun.